Originally posted 2018-03-22 01:59:26. Republished by Blog Post Promoter
ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in Yoruba
“Kí Kà ni Èdè Yorùbá” – “Counting or Numbers in Yoruba”
Yorùbá ni bi wọn ti ma a nka nkàn ki wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ si ka a ni èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ ṣe àyẹ̀wò kíkà ni èdè Yorùbá ni ojú ewé yi:
ENGLISH TRANSLATION
Counting or numbers in Yoruba before the introduction of counting in English. Check out counting or numbers’ pronunciation on this page.
Originally posted 2016-03-18 01:15:22. Republished by Blog Post Promoter
Bíbẹ Èkó wo fún Ọ̀sẹ̀ kan – Ọjọ́ kẹta: Visiting Lagos for one week – Day 3 (Yoruba Conversation)
Apá Kinni – Part One
You can also download the conversation by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 3(mp3)
ONÍLÉ – HOST/HOSTESS & ÀLEJÒ (VISITOR) |
OHUN ṢÍṢE |
ENGLISH TRANSLATION HOST/HOSTESS AND THE VISITOR’S ACTIVITIES |
ONÍLÉ – HOST | Kan ilẹ̀kùn, Ẹkaarọ o, ṣé ẹ ti jí? | Knock on the door, Good morning. Are you awake? |
ÀLEJÒ – VISITOR | Bẹẹni, mo ti jí, Kaarọ. | Yes, I am awake. Good morning |
ONÍLÉ – HOST | Ẹjọ̀wọ́ ẹ tètè múra ká lè jáde ni wéré | Please dress up quickly to enable us go out on time |
ÀLEJÒ – VISITOR | Mo ti ṣe tán, mo mbọ. | I have finished dressing, I am coming |
ONÍLÉ – HOST | Ẹ jẹ́ ká jẹun aarọ kátó jáde lọ si ọjà. | Let us eat breakfast before going to the market |
ÀLEJÒ – VISITOR | Ó da, màá bá ẹ níbi ìjẹun | Okay, I will join you at the dining |
ONÍLÉ – HOST | Ó da, mo nreti. Iṣu àti ẹyin díndín lafẹ́ jẹ laarọ yi | Okay, I am waiting, We are having yam and fried egg for Breakfast. |
ONÍLÉ ATI – HOST & ÀLEJÒ – VISITOR | Ońlé àti Àlejò gba àdúrà, wọ́n sí bẹ̀rẹ̀ sí jẹun | The Host/Hostess and the Visitor prayed and they began to eat |
ÀLEJÒ – VISITOR | O ṣé, kú àlejò mi, mo gbádùn oúnjẹ naa | Thanks for hosting me, I enjoyed the meal |
ONÍLÉ – HOST | Ó yá ẹjẹ́ kí á tètè jáde lọ sí ọjà, nítorí ọjà méjì ni á fẹ́ dé. À kọ́kọ́ lọ sí ọjà Tẹ́júoṣó ni Yaba kí a tó padà sí Balógun láti ra àwọn ẹ̀bùn tí ẹ fẹ́ kó padà. | Its time, let us go out early to the market because I want us to get to two markets at Tejuoso in Yaba and Balogun to buy the gifts you are taking along on your return. |
ÀLEJÒ – VISITOR | O ṣé, ó tiyá, jẹ́ ká lọ | Thank you. I am ready let us go. |
Originally posted 2013-06-04 17:09:30. Republished by Blog Post Promoter
Ohun ti mo fẹ́ràn nipa Ìsimi Iparí Ọ̀sẹ̀ – What I love about the Weekend Break
Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ karun ti a ti bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé ni ọ̀sẹ̀, inú mi ma ń dùn nitori ilé-iwé ti pari ni agogo kan ọ̀sán, ti ìsimi bẹ̀rẹ̀.
Mo fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma nri àwọn òbí mi. Lati ọjọ́ Ajé titi dé ọjọ́ Ẹti, mi o ki ri ìyá àti bàbá mi nitori súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ni Èkó, wọn yio ti jade ni ilé ni kùtùkùtù òwúrọ̀ ki n tó ji, wọn yio pẹ́ wọlé lẹhin ti mo bá ti sùn.
Mo tún fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma ńsùn pẹ́, mo tún ma a ńri àyè wo eré lori amóhùn-máwòrán. Ni àkókò ilé-iwé, mo ni lati ji ni agogo mẹfa òwúrọ̀ lati múra fún ọkọ̀ ilé-iwé ti yio gbé mi ni agogo meje òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n ní igbà ìsimi ipari ọ̀sẹ̀, mo lè sùn di agogo mẹjọ òwúrọ̀. Ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìyá mi ma nṣe oriṣiriṣi oúnjẹ ti ó dùn, mo tún ma njẹun púpọ̀. Ni ọjọ́ Àikú (ọjọ́ ìsimi) bàbá mi ma ngbé wa lọ si ilé-ìjọ́sìn, lẹhin isin, a ma nlọ ki bàbá àti ìyá àgbà. Bàbá àti ìyá àgbà dára púpọ̀.
Ni ọjọ́ Àikú ti ìsimi ti fẹ́ pari, inú mi ki i dùn nigbati òbí mi bá sọ wi pé mo ni lati tètè sùn lati palẹ̀mọ́ fún ilé-iwé ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ajé.
ENGLISH LANGUAGE
On Friday the fifth day of schooling, I am always very happy because school closes at one o’clock in the afternoon when the weekend begins.
I love the weekend break because I get to see my parents. From Monday to Friday, I do not get to see my mother/mummy and father/daddy because in order to beat the Lagos traffic, they leave home for work before I wake up and return very late when I am asleep.
I also love the weekend break because I get to sleep longer and watch television too. During the school day, I wake up at six o’clock in the morning to get ready for the school bus that picks me up at seven o’clock in the morning. But during the weekend, I get to sleep till eight o’clock in the morning. Mummy cooks different types of meal on Saturday and I get to eat more. On Sunday, Daddy drives us to Church and after Church, we go to visit my grandparent. Grandpa and grandma are very nice.
I am not usually happy when I am told by my parent to go to bed early on Sunday in order to get ready for school on Monday.
Originally posted 2018-07-06 01:10:04. Republished by Blog Post Promoter
Kòkòrò – Names of Insects & Bugs in Yoruba
Kòkòrò jẹ́ ohun ẹ̀dá kékeré tó ni ìyẹ́, ti ó lè fò, òmíràn kò ni iyẹ́, ṣugbọn wọn ni ẹsẹ̀ mẹfa. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ, àwòrán àti pi pè ni ojú ewé wọnyi.
ENGLISH TRANSLATION
Insects & Bugs are small creatures, many of them have feathers, some have no feathers, but they have six legs. Check out the examples in the pictures and the pronunciation on the slides below:
Originally posted 2014-01-29 01:18:16. Republished by Blog Post Promoter
Ẹ̀̀ya orí ni èdè Yorùbá – Parts of Head in Yoruba Language
Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀. Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè. A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò.
ENGLISH TRANSLATION
It is important to be familiar with the names of parts of the body in learning a language because it is often embedded in conversation. Understanding these names would enhance the knowledge of Yoruba by those who love to learn the language. We hope that the pictures and the Yoruba pronunciation on these slides would be useful.
Originally posted 2013-07-16 01:52:39. Republished by Blog Post Promoter
Orúkọ Ẹranko a fàyà fà tabi jomijòkè ni èdè Yorùbá: Names of Reptiles and Amphibious Animals in Yoruba Language
Gẹgẹbi àpè júwe, ẹranko a fàyà fà jẹ ẹranko ti ó ni àwọ̀, omiran ni oro, omiran ni ikarawun, wọn si ńyé ẹyin. Bi Ejò, àti Ákẽke ti ni oró bẹ̃ ni Àjàpá àti Ìgbín ni ikarawun. Fún àpẹrẹ irú àwọn ẹran wọnyi ni: Ejò, Àjàpá, Alangba àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Ẹ wo àwòrán àti pipe irú àwọn ẹranko wọnyi ni ojú ewé yi.
ENGLISH TRANSLATION
According to the description, reptiles are animals with skin, some are poisonous, while some have shell and lay eggs. As snake and scorpion are poisonous so also are the tortoise and snail have shell. For example: Snakes, Tortoise, lizard etc. Check out the pictures and pronunciation of these reptiles in the slides below.
Ẹranko a fàyà fà tabi jomijòkè – Reptiles
Originally posted 2013-12-27 00:26:23. Republished by Blog Post Promoter
BÍBẸ̀ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN (ỌJỌ́ KEJÌ) – Visiting Lagos for a Week (Day 2)
You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 2(mp3)
ỌJỌ́ KEJÌ – DAY TWO | ||
ONÍLÉ (HOST OR HOSTESS) ÀLEJÒ (VISITOR) | Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ LÃRIN ONÍLÉ ÀTI ÀLEJÒ | ENGLISH TRANSLATION: CONVERSATION BETWEEN THE HOST/HOSTESS AND THE VISITOR |
ONÍLÉ – HOST | Kan ilẹ̀kùn | Knock on the door |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Tani? | Who is it? |
ONÍLÉ – HOST | Èmi ni o. Ẹkãrọ, ṣé ẹ sùn dãda? | It is me. Goodmorning. Hope you slept well? |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Bẹ̃ni, mo sùn dãda, a dúpẹ́ | Yes, I slept well, thank you. |
ONÍLÉ – HOST | Ãgo meje ti lù, mo fẹ́ má lọ si ibi iṣẹ́. | It is seven o’clock, I want to go to work |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Ah, ãgo meje ti sáré lù, mo mbọ mo ti múra tán | Ah! Its already 7 a.m? I am coming, I have finished dressing |
ONÍLÉ – HOST | Ó da, mò ndúró. Oúnje ãrọ ti ṣetán | Okay, I am waiting, breakfast is ready. |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Kíla fẹ́ jẹ lãrọ yi? | What are we eating this morning? |
ONILE – HOST | Ògì àti àkàrà ni. Ó yá, ẹ jẹ́ká jẹun | It is Indian Corn Starch and Fried Bean Cake |
Onílé àti Àlejò gba àdúrà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹun | The Host/Hostess and Visitor prayed and they began to eat | |
ÀLEJÒ (VISITOR) | O se, ku alejo mi, mo gbadun ounje na. Fi abọ́ sílẹ̃, ma palẹ̀mọ́. | Thanks for hosting me, I enjoyed the meal. Leave the plates, I will clear up. |
ONÍLÉ – HOST | Mo ti fẹ́ mã lọ si ibi iṣẹ́. Mo ti gbé ẹ̀wà rírò àti gãri si ibi ìdáná fún oúnjẹ ọ̀sán. Tí ẹ bá́́ simi tán ti ẹ fẹ́ najú ladugbo, ẹ pe Folúṣọ́ ní ilé keji kó sì yín jáde. | I am about going to work, I have kept stewed beans and gari (coarsed casava flour) in the kitchen for lunch. If you want to take a stroll around the neigbhourhood, call Foluso from the next house to accompany you. |
ÀLEJÒ (VISITOR) | O ṣé, ódàbọ̀. Ó rẹ̀ mí, mã sùn díẹ̀ si ṣùgbọ́n ma pe Folúṣọ́ tí mo bájí | Thank you. Goodbye. I am tired, I will sleep a little later and call Foluso when I wake. |
ONÍLÉ – HOST | Ódàbọ̀. Mà ṣetán níbi iṣẹ ni ãgo marun àbọ̀. Ó yẹ ki ndélé títí ãgo meje tíkò bá sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ | Goodbye. I will close from work at 5.30pm. I hope to get home at about 7.00pm if there is no traffic jam. |
ÀLEJÒ (VISITOR) | O da bẹ. A dú́pẹ́ | Its fine, thank you. |
ONÍLÉ – HOST | Ẹkúilé o. Ṣé ẹ simi dãda? | Greetings. Hope you had a good rest? |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Kãbọ, ó mà yá, o ti dé lãgo mẹ́fà àbọ̀. Mo simi dãda, Folúṣọ́ mú mi jáde sí Àdúgbò. | Welcome, your return at 6.30pm was quick. I went around the neighbourhood with Foluso. |
ONÍLÉ – HOST | Bẹ̃ni, kò sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ rárá. Ṣé ebi ti npa yín? | Yes, there was no traffic jam at all. Are you hungry? |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Rárá, mo ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ ọ̀sán tí ó gbé sílẹ̀ ni bi ãgo mẹ́fà ni. | No, I have just eaten the lunch you left for me at about 6.00pm. |
ONÍLÉ – HOST | O dã bẹ. Èmi nã ti jẹun níbiṣẹ́. Mo ma lọ palẹ̀mọ́ lati sùn ṣùgbọ́n mi o lọ síbi iṣẹ́ lọla a ṣeré jáde. Ódàárọ̀. | That is good. I have also eaten at work. I am going to get ready to sleep but I am not going to work tomorrow, we will go for outing. Goodnight. |
ÀLEJÒ (VISITOR) | Ódàárọ̀ | Goodnight. |
Originally posted 2013-04-05 20:52:07. Republished by Blog Post Promoter
ATỌ́NÀ LÉDÈ YORÙBÁ – Cardinal Directions in Yoruba
Originally posted 2013-04-16 19:01:07. Republished by Blog Post Promoter
Tọ́jú Ìwà Rẹ Ọ̀rẹ́ Mi – Ọ̀rọ̀-orin lati Ìwé Olóògbé Olóyè J.F. Ọdúnjọ – My friend, care about your character – a poem by late Chief J.F. Odunjo
Ọ̀rọ̀-orin yi jẹ ikan ninú àwọn àkọ́-sórí ni ilé-ìwé alakọbẹrẹ ni ilẹ̀ Yorùbá ni igbà ti ile-iwe àpapọ̀ yè koro. Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ti gbogbo ilé-ìwé ti kọ èdè abínibí silẹ̀, ọ̀rọ̀-orin ti kò ni ìtumọ̀ ni àṣà àti èdè Yorùbá ni àwọn ọmọ ilé-ìwé ńkà. Tàbi bawo ni “afárá tó wó lulẹ̀ ni ìlú-ọba” ṣe kan ọmọ ti kò ri iná, omi mímọ́ mu, ọ̀nà gidi, ilé-ìwé ti idaji rẹ ti wó, tàbi ti kò ri afárá ri ni abúlé rẹ̀, ti jẹ́? A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ti ó ṣe òfin ki wọn bẹ̀rẹ̀ si kọ́ èdè àti àṣà Yorùbá ni gbogbo ilé-ìwé pátápátá. A lérò wi pé eleyi yi o jẹ́ ki àwọn olùkọ́ àti ọmọ ilé-ìwé bẹ̀rẹ̀ si kọ́ ọ̀rọ̀-orin tàbi àkọ́-sórí ti ó mú ọgbọ́n dáni. Ẹ ṣe àyẹ̀wò ki kọ àti ki kà ọ̀rọ̀-orin yi.
Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi;
Ọlá a má ṣi lọ n’ilé ẹni’
Ẹwà a si ma ṣi l’ára ènìà
Olówó òní ńd’olòṣì b’ó d’ọ̀la
Òkun l’ọlá; òkun n’igbi ọrọ̀
Gbogbo wọn ló ńṣí lọ n’ilé ẹni;
Ṣùgbọ́n ìwà̀ ni mbá ni dé sare’e
Owó kò jẹ́ nkan fún ni,
Ìwà l’ẹwà ọmọ ènìà.
Bi o lówó bi o kò n’íwà ńkọ́?
Tani jẹ f’inú tán ẹ bá ṣ’ohun rere?
Tàbi ki o jẹ́ obìnrin rọ̀gbọ̀dọ́;
Ti o bá jìnà s’ìwà ti ẹ̀dá ńfẹ́,
Tani jẹ́ fẹ́ ọ s’ílé bi aya?
Tàbi ki o jẹ oníjìbìtì ènìà;
Bi o tilẹ̀ mọ ìwé àmọ̀dájú,
Tani jẹ́ gbé’ṣé ajé fún ọ ṣe?
Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi,
Ìwà kò sí, ẹ̀kọ́ dègbé;
Gbogbo ayé ni ‘nfẹ́ ‘ni t’ó jẹ́ rere.
ENGLISH TRANSLATION
This is one of the poems memorised by primary school pupils when there was quality public education. But nowadays, when schools have abandoned mother tongue, children are now taught meaningless foreign poems. Or how relevant is the poem about “London Bridge falling down” to a child who has no access to electricity/power, clean potable water, good road, dilapidated classrooms, or has never seen a bridge in her little village? Kudos to the Lagos House of Assembly and the Governor for legislating a law making the teaching and learning of Yoruba language and culture compulsory in all Lagos schools. It is hoped that this effort by Lagos State will encourage both the teachers and pupils to return to learning poems that are relevant and sensible poems. See below the words and recital of the poem.
Care about your character, my friend;
Wealth do depart from one’s lineage
Beauty do fade from people
A rich man today could end up in poverty tomorrow,
Riches is like ocean, ocean is like the depth of wealth
All do depart from lineage
But only character follows one to the grave
Money is nothing
Character is the beauty of a person
What if you are rich without any moral principle?
Who will confide in you for a worthy cause?
Or if you are a woman of paragon beauty;
Yet far away from people’s expected moral standard,
Who will marry such as a wife?
Or if you are a con-artist;
Even when you are highly educated,
Who will entrust you with business?
Care about your character, my friend,
In the absence of character, education is futile,
Everyone loves a person with good character.
Originally posted 2018-08-10 02:12:55. Republished by Blog Post Promoter
KÍKÀ NÍ YORÙBÁ: COUNTING IN YORUBA – NUMBERS 1 TO 20
KÍKÀ ỌJÀ NIPARI Ọ̀SẸ̀ – END OF WEEK STOCK TAKING: LEARNING NUMBERS 1 TO 20
You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: counting 1 -20 in Yoruba recited
0 | Òdo | Àlùbọ́sà titán | Zero onions (Out of Stock) |
1 | Õkan | Àpò Iyọ̀ kan | One bag of salt |
2 | Ẽji | Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ méjì | Two bunches of bananas |
3 | Ẹ̃ta | Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà mẹ́ta | Three bunches of Plantains |
4 | Ẹ̃rin | Garawa Epo Òyìnbó mẹ́rin | Four tins of kerosene |
5 | Ãrun | Garawa Òróró marun | Five tins of vegetable oil |
6 | Ẹ̀fà | Garawa Epo pupa mẹ́fà | Six tins of palm oil |
7 | Ẽje | Igo Epo Òyìnbó meje | Seven bottles of kerosene |
8 | Ẹ̀jo | Igo Òróró mẹjọ | Eight bottles of vegetable oil |
9 | Ẹ̀sán | Igo Epo pupa mẹsan | Nine bottles of palm Oil |
10 | Ẹ̀wá | Ẹja gbígbẹ mẹwa | Ten pieces of dry fish |
11 | Ọ̀kànlá | Àpò Ẹ̀wà mọ́kànlá | Eleven bags of beans |
12 | Èjìlá | Àpò Èlùbọ́ méjìlá | Twelve bags of dry yam flour |
13 | Ẹ̀tàlá | Àpò Ìrẹsì mẹ́tàlá | Thirteen bags of rice |
14 | Ẹ̀rìnlá | Àpò Gãri mẹ́rìnlá | Fourteen bags of coarse cassava flour |
15 | Mẹ̃dogun | Àpò Àgbàdo mẹ̃dogun | Fifteen bags of maize |
16 | Ẹ̀rìndínlógún | Iṣu mẹ́rìndínlógún | Sixteen yams |
17 | Ẹ̀tàdínlógún | Àgbọn mẹ́tàdínlógún | Seventeen coconuts |
18 | Èjìdínlógún | Orógbó méjìdínlógún | Eighteen pods of bitter kola |
19 | Ọ̀kàndínlógún | Atare mọ́kàndínlógún | Nineteen alligator peppers |
20 | Ogún | Obì Ogún | Twenty kola nuts |
Originally posted 2013-03-12 22:25:14. Republished by Blog Post Promoter
Ìkíni ni Èdè Yorùbá – Greetings in Yoruba Language
Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀ Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si abala ojú ìwé yi, àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò fún yin.
ENGLISH TRANSLATION
As a sign of respect, the Yoruba have greetings for any time of the day, special events and ceremonies. We hope you will enjoy some of the greetings below in the slides and voice recordings.
Originally posted 2013-07-04 23:41:35. Republished by Blog Post Promoter
“Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi: Ibere ti ó wọ́pọ́ ni èdè Yorùba” – “Questions calls for answer: Common questions in Yoruba language”
Ọpọlọpọ ibere ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu “ọfọ̀ – K”. Yàtọ̀ fún li lò ọfọ̀ yi ninú ọ̀rọ̀, orúkọ enia tàbi ẹranko, ọfọ̀ yi wọ́pọ̀ fún li lò fún ibere. Fún àpẹrẹ, orúkọ enia ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọfọ̀ – K ni: Kíkẹ́lọmọ, Kilanko, Kẹlẹkọ, Kẹ́mi, Kòsọ́kọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ; orúkọ ẹranko – Kiniun, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Kòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn irú ibere àti èsì wọnyi ni ojú ewé yi.
[slideboom id=1069722&w=425&h=370]
Originally posted 2015-01-13 09:00:46. Republished by Blog Post Promoter
Àròkọ ni Èdè Yorùbá – Essay in Yoruba Language
Idi ti a fi bẹ̀rẹ̀ si kọ iwé ni èdè Yorùbá lóri ayélujára ni lati jẹ́ ki ẹnikẹ́ni ti ó fẹ́ mọ̀ nipa èdè àti àṣà Yorùbá ri ìrànlọ́wọ́ lóri ayélujára.
A ò bẹ̀rẹ̀ si kọ àwọn àròkọ ni èdè Yorùbá lati ran àwọn ọmọ ilé-iwé lọ́wọ́ nipa ki kọ àpẹrẹ oriṣiriṣi àròkọ ni èdè Yorùbá àti itumọ̀ rẹ ni èdè Gẹ̀ẹ́si. A o si tún ka a ni èdè Yorùbá fún ìrànlọ́wọ́ ẹni ti ó fẹ mọ bi ohun ti lè ka a, ṣùgbọ́n kò wà fún àdàkọ.
ENGLISH TRANSLATION
Why The Yoruba Blog is creating a category for Essay in Yoruba language on the internet is to make available on line such resources for those who may be interested.
We shall begin to publish various samples of essay in Yoruba language in order to assist students, interpreted the essay as well as an audio recording of the essay in Yoruba, however, it is not to be copied.
Originally posted 2018-06-15 19:19:46. Republished by Blog Post Promoter
Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday
Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.
Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó. Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn. A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà. Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.
Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ. Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀. Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá. Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.
Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó. Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi. Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde. Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn àwọn àgbàlagbà. Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin. Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́. Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ. A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.
Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile. Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.
ENGLISH TRANSLATION
I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos.
Lagos is a very big city, with many tall buildings, so much various vehicles than in my home town. My uncle’s house is very big. I was given a room to myself. My room had a bathroom and toilet of its own.
My father and mother took me to Ikare-Akoko garage in Ondo State where I boarded public transport to Lagos and from that experience, I discovered that Lagos is so far from my home town. Among the towns I saw on the way were, Owo, Akure, Ile-Ife and Ibadan. We stopped over at Ilesa junction to buy bean fritters. My uncle and his wife were at hand at Ojota motor-park in Lagos to drive me to their home.
Every day, my uncle and his wife took me on a visit to various places in Lagos. On Good Friday, I was taken to church, the service was a sober one as a play on the crucifixion of Jesus was acted, but on Easter Sunday, the service was beautiful as there were many gaily dressed people in the church. I wore one of the newly clothes my uncle’s wife bought for me for Easter celebration. From the Sunday school, we as children joined the main church with dancing. At the end of the church service we were all served food (containing rice and big chicken lap). On Easter Monday (known as Galilee), we went for picnic at the beach. At first I was afraid of seeing such a large expanse of body of water, but later as I noticed that there were many people including children at the beach, my fear was gone. We ate different types of food, we danced and I rode a horse at the beach.
The school holiday was almost over, after two weeks, my uncle and his wife took me back to the bus terminal with various gifts for people at my home town. I was sad, I did not want to go back to my home town because I had so much fun in Lagos.
Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter
ABD YORÙBÁ – Yoruba Alphabet
“ABD”, ìbẹ̀rẹ̀ iwé kikà ni èdè Yorùbá – Yoruba Alphabets “ABD” is the beginning of Yoruba education.
Bi ọmọdé bá bẹrẹ ilé-iwé alakọbẹrẹ, èdè Yorùbá ni wọn fi nkọ ọmọ ni ilé-iwé lati iwé kini dé iwé kẹta. Ìbẹ̀rẹ̀ àti mọ̃ kọ, mọ̃ ka ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ki kọ àti pipe ABD. Ẹ ṣe àyẹ̀wò kikọ àti kikà ABD pẹ̀lú àwòrán ni ojú iwé yi.
ENGLISH TRANSLATION
When children are enrolled for primary education, they are taught in Yoruba language from Primary one to three. Learning how to write or read Yoruba language begins with writing and pronouncing ABD (Yoruba Alphabets). Check out writing and pronouncing Yoruba Alphabets – ABD with picture illustration on this page.
Learn the Yoruba alphabets with illustrations and pronunciation.

http://www.youtube.com/watch?v=ANUAiBkIAq4
Originally posted 2014-05-01 16:30:38. Republished by Blog Post Promoter
Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká – Effect of Environmental Pollution on Rapid Climate Change
Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ ṣe àkiyesi pe enia ndá kún yí yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà nitori èérí-àyíká. Ojú-ọjọ́ ti nyí padà lati ìgbà ti aláyé ti dá ayé, ṣùgbọ́n àyípadà ojú-ọjọ́ ni ayé òde òní yára ju ti ìgbà àtijọ́ lọ.
Yorùbá sọ wi pé “Ogun à sọ tẹ́lẹ̀, ki i pa arọ tó bá gbọ́n”. Àsìkò tó lati fi etí si ìkìlọ̀ Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ lóri yí yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà. Àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ ńké ìbòsí nipa ohun ti èérí àyíká ndá kún gbi gbóná àgbáyé àti ki ènìyàn ṣe àtúnṣe, lati din ìgbóná kù. Ìgbà gbogbo ni àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ Àyíká nṣe àlàyé yi ni Àjọ Ìfohùnṣọ̀kan Ìpínlẹ̀ Àgbáyé.
Lára ohun ti o ndá kún èérí àyíká, Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ tọ́ka si ọkọ̀, ẹ̀rọ mọ̀nà-mọ́ná, ẹ̀rọ-ilé-iṣẹ́, ṣ̀ugbọ́n èyí ti ó burú jù ni àwọn ohun ti wọ́n fi ike ṣe bi i: igò-ike, àpò-ike, ọ̀rá-ike, ike-ìṣeré àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bi ohun ti o ndá kún yi yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà.

Lára ohun ti o ndá kún èérí àyíká – Factors contributing to Environmental Pollution Courtesy@theyorubablog
Ewé, ìwé tàbi páálí ti a kó sọnù, wúlò fún àyiká ju ọ̀rá ati ike igbàlódé lọ. Bi wọ́n bá da àwọn ohun ti wọ́n fi ike ṣe dànù si ààtàn tàbi si odò, ki i jẹrà bi ewé. Bi wọn da ewé si ilẹ́, yio da ilẹ́ padà lai ni ewu fún ekòló, igbin àti àwọn kòkòrò kékeré yókù. Bi wọn da ewé, ìwé tàbi páálí si inú omi/odò, kò léwu fún ẹja àti ohun ẹlẹmi inú omi/odò, bi ti ọ̀rá àti ike igbàlódé to léwu fún ẹja àti ẹranko inú odò.
Àwọn ohun ti a lè ṣe lati fi etí si ìkìlọ̀ àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀, ni ki a din li lo ọ̀rá ike àti ohun ti a fi ike ṣe kù bi a kò bá lè da dúró pátápátá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni ìlú Òyìnbó ló ti ṣe òfin lati din li lò ike kù, àwọn miran ti bẹ̀rẹ̀ si gba owó fún àpò-ike ni ọjá lati jẹ́ ki àwọn enia lo àpò àlòtúnlò. Bi ó bá ṣe kókó ki á pọ́n oúnjẹ, a lè lo ewé fi pọ́n, jú ọ̀rá tàbi ike lọ. Ki a fi páálí tàbi apẹ̀rẹ̀ ọparun kó ẹrù, lo àpò àlòtúnlò lati ra ọjà, ka lo ìkòkò alámọ̀ lati ṣe oúnjẹ tàbi tọ́jú oúnjẹ kó lè gbóná, àti ki a din li lo ike kù yio din yi yára bi ojú-ọjọ́ ti nyí padà kù.
Lára àtúnṣe ti ìjọba lè ṣe, ni ki òṣè̀lú ṣe òfin lati din èérí kù, ìpèsè ilé iṣẹ́ ti ó lè sọ àwọn ohun ti a fi ike ṣe di àlòtúnlò àti ki kó ẹ̀gbin ni àsìkò.
Ohun ti gbogbo ará ilu,́ pàtàki àwọn ọ̀dọ́ tún lè ṣe, ni ṣi ṣa ọ̀rá tàbi ike omi àti ohun ti wọn fi ike ṣe, ti o ti dá èérí rẹpẹtẹ si inú odò àti àyíká kúrò. Gbi gbin igi àti ṣe ètò fún àyè ti omi lè wọ́ si ni ìgbà òjò na a yio din ìgbóná àgbáyé kù.
http://www.theyorubablog.com/wp-content/uploads/2019/01/Voice_190114_2-1.3gp
ENGLISH TRANSLATION
Scientists observed that human activities are contributing to the rapid change of environment as a result of environmental pollution. From time immemorial, climate had always changed but the change in recent years has been more rapid than usual.
According to a Yoruba adage “a forewarn war does not kill a wise cripple”. It is time to heed the warnings on rapid climate change by Scientists. Scientist are sounding the alarm on the effect of environmental pollution on global warming and the need for human being to rectify the situation. The Environmental Scientist have been making presentation on climate change at the United Nations for sometime now.
Some of the factors contributing to environmental pollution are vehicles/automobile, electric generators, factory machines, but Scientist specifically pointed out among other things plastic or petrochemical products such as plastic bottles, plastic bags, plastic wraps, plastic toys etc as a major contributor to rapid climate change.
Leaf wrap, paper or cardboard boxes are more environmentally friendly unlike the plastic products that are used in modern time. Unlike plastic products, when leaf, paper or cardboard box are dumped on dumpsite, it decomposes without causing any danger to earthworm, snail and other small insects. Likewise, when various leaf wrap, paper or cardboard are dumped into the river/sea, it poses no danger like plastic products that are dangerous to fish and other sea creatures.
If the use of petrochemical products cannot be totally eradicated, some actions can be taken to address the warning by Scientist, to reduce drastically the use of plastic products such as plastic wrap/bags. Many European countries have enacted laws on the reduction of the use of plastic products, while some introduced tax on plastic bags in order to encourage the use of re-usable bags. If it is important to wrap food, leaf wrap should be used in place of plastic wrap. The use of re-usable bags should be encouraged, using bamboo basket, clay pots to cook and keep food warm and reducing the use of plastic products will contribute to reducing rapid climate change.
Some actions that can be taken by the government are, enacting laws that could reduce environmental pollution, creation of waste/garbage recycling plants to process plastic waste for reuse and timely waste/garbage disposal.
The people, particularly the youths should embark on clearing the plastic waste that has polluted the river and the environment. Planting of trees and creation of excess rain water collection pit in form of artificial lake could reduce the effect of global warming.
Originally posted 2019-01-15 00:58:39. Republished by Blog Post Promoter
ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in Yoruba
Originally posted 2018-03-22 01:59:26. Republished by Blog Post Promoter
Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in Youruba
Ohun ti mo fẹ́ràn nipa Ìsimi Iparí Ọ̀sẹ̀ – What I love about the Weekend Break
Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ karun ti a ti bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé ni ọ̀sẹ̀, inú mi ma ń dùn nitori ilé-iwé ti pari ni agogo kan ọ̀sán, ti ìsimi bẹ̀rẹ̀.
Mo fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma nri àwọn òbí mi. Lati ọjọ́ Ajé titi dé ọjọ́ Ẹti, mi o ki ri ìyá àti bàbá mi nitori súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ni Èkó, wọn yio ti jade ni ilé ni kùtùkùtù òwúrọ̀ ki n tó ji, wọn yio pẹ́ wọlé lẹhin ti mo bá ti sùn.
Mo tún fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma ńsùn pẹ́, mo tún ma a ńri àyè wo eré lori amóhùn-máwòrán. Ni àkókò ilé-iwé, mo ni lati ji ni agogo mẹfa òwúrọ̀ lati múra fún ọkọ̀ ilé-iwé ti yio gbé mi ni agogo meje òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n ní igbà ìsimi ipari ọ̀sẹ̀, mo lè sùn di agogo mẹjọ òwúrọ̀. Ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìyá mi ma nṣe oriṣiriṣi oúnjẹ ti ó dùn, mo tún ma njẹun púpọ̀. Ni ọjọ́ Àikú (ọjọ́ ìsimi) bàbá mi ma ngbé wa lọ si ilé-ìjọ́sìn, lẹhin isin, a ma nlọ ki bàbá àti ìyá àgbà. Bàbá àti ìyá àgbà dára púpọ̀.
Ni ọjọ́ Àikú ti ìsimi ti fẹ́ pari, inú mi ki i dùn nigbati òbí mi bá sọ wi pé mo ni lati tètè sùn lati palẹ̀mọ́ fún ilé-iwé ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ajé.
ENGLISH LANGUAGE
On Friday the fifth day of schooling, I am always very happy because school closes at one o’clock in the afternoon when the weekend begins.
I love the weekend break because I get to see my parents. From Monday to Friday, I do not get to see my mother/mummy and father/daddy because in order to beat the Lagos traffic, they leave home for work before I wake up and return very late when I am asleep.
I also love the weekend break because I get to sleep longer and watch television too. During the school day, I wake up at six o’clock in the morning to get ready for the school bus that picks me up at seven o’clock in the morning. But during the weekend, I get to sleep till eight o’clock in the morning. Mummy cooks different types of meal on Saturday and I get to eat more. On Sunday, Daddy drives us to Church and after Church, we go to visit my grandparent. Grandpa and grandma are very nice.
I am not usually happy when I am told by my parent to go to bed early on Sunday in order to get ready for school on Monday.
Originally posted 2018-07-06 01:10:04. Republished by Blog Post Promoter