Quantcast
Viewing all 1414 articles
Browse latest View live

ORÚKỌ ỌJỌ́: Days of the Week in YorubaOriginally Posted on March 19, 2013, last updated on March 26, 2013 and reposted on July 6, 2019

Below are the Yoruba days of the week. Of course it is worth noting that very few native Yoruba speakers use these words in conversation.

 

SUNDAY                               ÀÌKÚ

MONDAY                             AJÉ

TUESDAY                             ÌṢẸ́GUN

WEDNESDAY                      ỌJỌ́RÚ

THURSDAY                          ỌJỌ́BỌ̀

FRIDAY                                 ẸTÌ

SATURDAY                          ÀBÁMẸ́TA

Originally posted 2013-03-19 22:33:05. Republished by Blog Post Promoter


BÍBẸ̀ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN (ỌJỌ́ KEJÌ) – Visiting Lagos for a Week (Day 2)Originally Posted on April 5, 2013, last updated on April 11, 2013 and reposted on July 8, 2019

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 2(mp3)

JỌ́ KEJÌ – DAY TWO
ONÍLÉ (HOST OR HOSTESS) ÀLEJÒ (VISITOR) Ọ̀RỌ̀ SÍS LÃRIN ONÍLÉ ÀTI ÀLEJÒ ENGLISH TRANSLATION: CONVERSATION   BETWEEN THE HOST/HOSTESS AND THE VISITOR
ONÍLÉ – HOST Kan ilẹ̀kùn Knock on the door
ÀLEJÒ (VISITOR) Tani? Who is it?
ONÍLÉ – HOST Èmi ni o.    Ẹkãrọ, ṣé ẹ sùn dãda? It is me.    Goodmorning.  Hope you slept   well?
ÀLEJÒ (VISITOR) Bẹ̃ni, mo sùn dãda, a dúpẹ́ Yes, I slept well, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ãgo meje ti lù, mo fẹ́ má lọ si ibi iṣẹ́. It is seven o’clock, I want to go to work
ÀLEJÒ (VISITOR) Ah, ãgo meje ti sáré lù, mo mbọ mo ti múra tán Ah! Its already 7 a.m?  I am coming, I have finished dressing
ONÍLÉ – HOST Ó da, mò ndúró.    Oúnje ãrọ ti ṣetán Okay, I am waiting, breakfast is ready.
ÀLEJÒ (VISITOR) Kíla fẹ́ jẹ lãrọ yi? What are we eating this morning?
ONILE – HOST Ògì àti àkàrà ni.    Ó yá, ẹ jẹ́ká jẹun It is Indian Corn Starch and Fried Bean Cake
Onílé àti Àlejò gba àdúrà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹun The Host/Hostess and Visitor prayed and they began to eat
ÀLEJÒ (VISITOR) O se, ku alejo mi, mo gbadun ounje na. Fi abọ́ sílẹ̃, ma palẹ̀mọ́. Thanks for hosting me, I enjoyed the meal.  Leave the plates, I will clear up.
ONÍLÉ – HOST Mo ti fẹ́ mã lọ si ibi iṣẹ́.    Mo ti gbé ẹ̀wà rírò àti gãri si ibi ìdáná fún oúnjẹ ọ̀sán.    Tí ẹ bá́́ simi tán ti ẹ fẹ́ najú ladugbo, ẹ pe Folúṣọ́ ní ilé keji kó sì yín jáde. I am about going to work, I have kept stewed beans   and gari (coarsed casava flour) in the kitchen for lunch.  If you want to take a stroll around the   neigbhourhood, call Foluso from the next house to accompany you.
ÀLEJÒ (VISITOR) O ṣé, ódàbọ̀. Ó rẹ̀ mí, mã sùn díẹ̀ si ṣùgbọ́n ma pe Folúṣọ́ tí mo bájí Thank you.    Goodbye.  I am tired, I will   sleep a little later and call Foluso when I wake.
ONÍLÉ – HOST Ódàbọ̀.    Mà ṣetán níbi iṣẹ ni ãgo marun àbọ̀. Ó yẹ ki ndélé títí ãgo meje tíkò bá sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ Goodbye.  I   will close from work at 5.30pm.  I hope   to get home at about 7.00pm if there is no traffic jam.
ÀLEJÒ (VISITOR) O da bẹ. A dú́pẹ́ Its fine, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ẹkúilé o.  Ṣé ẹ simi dãda? Greetings.    Hope you had a good rest?
ÀLEJÒ (VISITOR) Kãbọ, ó mà yá, o ti dé lãgo mẹ́fà àbọ̀.    Mo simi dãda, Folúṣọ́ mú mi jáde sí Àdúgbò. Welcome, your return at 6.30pm was quick.  I went around the neighbourhood with   Foluso.
ONÍLÉ – HOST Bẹ̃ni, kò sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ rárá. Ṣé ebi ti npa yín? Yes, there was no traffic jam at all.  Are you hungry?
ÀLEJÒ (VISITOR) Rárá, mo ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ ọ̀sán tí ó gbé sílẹ̀ ni bi ãgo mẹ́fà ni. No, I have just eaten the lunch you left for me at about 6.00pm.
ONÍLÉ – HOST O dã bẹ.    Èmi nã ti jẹun níbiṣẹ́.  Mo ma lọ palẹ̀mọ́ lati sùn ṣùgbọ́n mi o lọ síbi iṣẹ́ lọla  a ṣeré jáde. Ódàárọ̀. That is good. I have also eaten at work.  I am going    to get ready to sleep but I am not going to work tomorrow, we will go   for outing. Goodnight.
ÀLEJÒ (VISITOR) Ódàárọ̀ Goodnight.

Originally posted 2013-04-05 20:52:07. Republished by Blog Post Promoter

KÍKÀ NÍ YORÙBÁ: COUNTING IN YORUBA – NUMBERS 1 TO 20Originally Posted on March 12, 2013, last updated on March 18, 2013 and reposted on July 8, 2019

KÍKÀ ỌJÀ NIPARI Ọ̀SẸ̀ – END OF WEEK STOCK TAKING: LEARNING NUMBERS 1 TO 20

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: counting 1 -20 in Yoruba recited

0 Òdo Àlùbọ́sà titán Zero onions (Out of Stock)
1 Õkan Àpò Iyọ̀ kan One bag of salt
2 Ẽji Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ méjì Two bunches of bananas
3 Ẹ̃ta Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀  àgbagbà mẹ́ta Three bunches of Plantains
4 Ẹ̃rin Garawa Epo Òyìnbó mẹ́rin Four tins of kerosene
5 Ãrun Garawa Òróró marun Five tins of vegetable oil
6 Ẹ̀fà Garawa Epo pupa mẹ́fà Six tins of palm oil
7 Ẽje Igo Epo Òyìnbó meje Seven bottles of kerosene
8 Ẹ̀jo Igo Òróró mj Eight bottles of vegetable oil
9 Ẹ̀sán Igo Epo pupa msan Nine bottles of palm Oil
10 Ẹ̀wá Ẹja gbígbẹ mwa Ten pieces of dry fish
11 Ọ̀kànlá Àpò Ẹ̀wà mọ́kànlá Eleven bags of beans
12 Èjìlá Àpò Èlùbọ́ méjìlá Twelve bags of dry yam flour
13 Ẹ̀tàlá Àpò Ìrẹsì mẹ́tàlá Thirteen bags of rice
14 Ẹ̀rìnlá Àpò Gãri mẹ́rìnlá Fourteen bags of coarse cassava flour
15 Mẹ̃dogun Àpò Àgbàdo mẹ̃dogun Fifteen bags of maize
16 Ẹ̀rìndínlógún Iṣu mẹ́rìndínlógún Sixteen yams
17 Ẹ̀tàdínlógún Àgbọn mẹ́tàdínlógún Seventeen coconuts
18 Èjìdínlógún Orógbó méjìdínlógún Eighteen pods of bitter kola
19 Ọ̀kàndínlógún Atare mọ́kàndínlógún Nineteen alligator peppers
20 Ogún Obì Ogún Twenty kola nuts

Originally posted 2013-03-12 22:25:14. Republished by Blog Post Promoter

“Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi: Ibere ti ó wọ́pọ́ ni èdè Yorùba” – “Questions calls for answer: Common questions in Yoruba language”Originally Posted on January 13, 2015, last updated on January 12, 2015 and reposted on July 10, 2019

Ọpọlọpọ ibere ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu “ọfọ̀ – K”.  Yàtọ̀ fún li lò ọfọ̀ yi ninú ọ̀rọ̀, orúkọ enia tàbi ẹranko, ọfọ̀ yi wọ́pọ̀ fún li lò fún ibere.  Fún àpẹrẹ, orúkọ enia ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọfọ̀ – K ni: Kíkẹ́lọmọ, Kilanko, Kẹlẹkọ, Kẹ́mi, Kòsọ́kọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ; orúkọ ẹranko – Kiniun, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Kòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn irú ibere àti èsì wọnyi ni ojú ewé yi.

Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi – Slides

View more presentations or Upload your own.

[slideboom id=1069722&w=425&h=370]

Originally posted 2015-01-13 09:00:46. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀̀ya orí ni èdè Yorùbá – Parts of Head in Yoruba LanguageOriginally Posted on July 16, 2013, last updated on July 16, 2013 and reposted on July 11, 2019

Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀.  Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè.  A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò.

ENGLISH TRANSLATION

It is important to be familiar with the names of parts of the body in learning a language because it is often embedded in conversation.  Understanding these names would enhance the knowledge of Yoruba by those who love to learn the language.  We hope that the pictures and the Yoruba pronunciation on these slides would be useful.

Originally posted 2013-07-16 01:52:39. Republished by Blog Post Promoter

“Ògòngò lọba ẹiyẹ” – “Ostrich is the King of Birds”Originally Posted on October 17, 2014, last updated on October 16, 2014 and reposted on July 12, 2019

Image may be NSFW.
Clik here to view.
Ògòngò - Ostrich.  Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò – Ostrich. Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù.  Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku.  Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀.  Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ.  Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nitori bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn.

Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé (ẹiyẹ ọsin)ni, Adiẹ (Àkùkọ àti Àgbébọ̀ adiẹ), Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó/Odidẹrẹ́ àti Ọ̀kín.  Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni: Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Igún/Àkàlàmàgbò àti Lekeleke.  Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn.  Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi.

Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.

Agbe ló laró ————— ki rá ùn aró
Àlùkò ló losùn ———— ki rá ùn osùn
Lekeleke ló lẹfun ——– ki rá ùn ẹfun
Ka má rá ùn owó, ka má rá ùn ọmọ
Ohun tá ó jẹ, tá ó mu, kò mà ni wọn wa ò.

ENGLISH TRANSLATION

Ostrich is the biggest and has the largest eggs among the birds.  The long neck and legs made it taller than all the other birds.  Ostrich is also the fastest runner on land more than all the birds.  This is why Yoruba crowned Ostrich as the King of Birds.  Many wild birds such as Ostrich are almost extinct as a result of the expansion of towns and cities displacing the wild birds which can now be seen at the Zoo.

There are various types of birds in Yoruba land, the most common at home or in town (domestic birds) are: Chicken (Cock and Hen), Duck, Pigeon, Guinea Fowl, Parrot, and Peacock.  The common wild birds that are known in the town or communities are: Falcon/Kite, Eagle, Owl, Vulture and Cattle-egret.  Birds are of various colours, one species of bird can come in various colours, while some are black like the dye, some are red like the camwood, and some are white, but the Yoruba song on this page depicted the common colours that are peculiar with some species of birds.  For example, Cattle-Egret are white like chalk, Blue Turaco are coloured like the dye and Red Turaco are reddish like the camwood.   Check out the pictures and prononciation of some of the birds that are common in Yoruba land on this page.

Originally posted 2014-10-17 12:27:16. Republished by Blog Post Promoter

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter HolidayOriginally Posted on June 15, 2018, last updated on June 15, 2018 and reposted on July 15, 2019

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos.

Lagos is a very big city, with many tall buildings, so much various vehicles than in my home town.  My uncle’s house is very big.  I was given a room to myself.  My room had a bathroom and toilet of its own.

My father and mother took me to Ikare-Akoko garage in Ondo State where I boarded public transport to Lagos and from that experience, I discovered that Lagos is so far from my home town.  Among the towns I saw on the way were, Owo, Akure, Ile-Ife and Ibadan.  We stopped over at Ilesa junction to buy bean fritters. My uncle and his wife were at hand at Ojota motor-park in Lagos to drive me to their home.

Every day, my uncle and his wife took me on a visit to various places in Lagos.  On Good Friday, I was taken to church, the service was a sober one as a play on the crucifixion of Jesus was acted, but on Easter Sunday, the service was beautiful as there were many gaily dressed people in the church. I wore one of the newly clothes my uncle’s wife bought for me for Easter celebration.  From the Sunday school, we as children joined the main church with dancing.  At the end of the church service we were all served food (containing rice and big chicken lap).  On Easter Monday (known as Galilee), we went for picnic at the beach.  At first I was afraid of seeing such a large expanse of body of water, but later as I noticed that there were many people including children at the beach, my fear was gone.  We ate different types of food, we danced and I rode a horse at the beach.

The school holiday was almost over, after two weeks, my uncle and his wife took me back to the bus terminal with various gifts for people at my home town.  I was sad, I did not want to go back to my home town because I had so much fun in Lagos.

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in YourubaOriginally Posted on October 17, 2014, last updated on October 16, 2014 and reposted on July 19, 2019


ATỌ́NÀ LÉDÈ YORÙBÁ – Cardinal Directions in YorubaOriginally Posted on April 16, 2013, last updated on August 18, 2015 and reposted on July 19, 2019

Ẹ̀kọ́-ìṣirò ni èdè Yorùbá – Simple Arithmetic in Yoruba LanguageOriginally Posted on March 22, 2016, last updated on April 8, 2016 and reposted on July 20, 2019

Yorùbá ni bi wọn ti ma nṣe ìṣirò ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ka ni èdè Gẹ̀ẹ́sì.  Akọ̀wé yi kọ ìṣirò ki ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé lọdọ ìyá rẹ̀ àgbà.  Nígbàtí ìyá-àgbà bá nṣe iṣẹ́ òwú “Sányán” lọ́wọ́, a ṣa òkúta wẹ́wẹ́ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ lati ṣe ìṣirò ni èdè Yorùbá.  Is̀irò ni èdè Yorùbá ti fẹ́ di ohun ìgbàgbé, nitori àwọn ọmọ ayé òde òní kò rí ẹni kọ́ wọn ni ilé tàbi ilé-ìwé, nitorina ni a ṣe ṣe àkọọ́lẹ̀ ìṣirò yi si ojú ewé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba were doing Arithmetic before learning it in English.  This Publisher learnt simple Arithmetic from her grandmother before enrolling in primary school.  As the Grandmother was processing “raw silk”, she would gather pebbles for her granddaughter for the purpose of teaching simple Arithmetic in Yoruba Language.  Arithmetic in Yoruba Language is almost extinct, because children nowadays, have no one to teach them at home or at school, hence the documentation of these simple Arithmetic in Yoruba Language as can be viewed on this page.

Originally posted 2016-03-22 07:10:47. Republished by Blog Post Promoter

“ABD” ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè Yorùbá́ – Alphabets is the beginning of words in Yoruba LanguageOriginally Posted on February 4, 2014, last updated on February 4, 2014 and reposted on July 20, 2019

Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa “abd” ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kikọ ni èdè Yorùbá sẹhin, a tu kọ fún iranti rẹ ni pi pè, kikọ àti lati tọka si ìyàtọ̀ larin ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́si.

Fún àpẹrẹ, èdè Gẹ̀ẹ́si ni ibere oro mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nigbati èdè Yorùbá ni marun-din-lọgbọn.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn àwòrán ti o wa ni oju ewe wonyi:

ENGLISH TRANSLATION

Even though we have written about Yoruba Alphabets in the past, it is being re-written to remind  readers on how it is pronounced, written and to point out the difference between the Yoruba and English Alphabets.

For example, English Alphabets are made up of twenty-six letter while Yoruba Alphabets are twenty-five.  Check out the slides on this page.

Diference between Yoruba & English Alphabets

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2014-02-04 19:04:40. Republished by Blog Post Promoter

Ìbà Àkọ́dá – Reverence to the First BeingOriginally Posted on October 2, 2015, last updated on October 2, 2015 and reposted on July 20, 2019

Image may be NSFW.
Clik here to view.
Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá - A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá – A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá
Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ
Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ
Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ
Alápáńlá tó so’lé ayé ró
Ṣe àtúntò ayé mi
Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ
Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀
Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ

Ìbà! ìbà!!

Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú
Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ
Ọmọ onínúure a má a pọ́njú
Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ
Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́
Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o
Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé
Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere
Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́
Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ

Ìbà! ìbà!!

Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò
ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú
ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu
Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú!
ọ̀rẹ́ kan tí mo ní
Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù!

Ìbà! ìbà!!

ENGLISH TRANSLATION

Reverence to the First Being, reverence to the Creator
I will revere Him today; let my reverence be
In times of plenty, in times of scarcity
I come with a heart of thanksgiving; let my reverence be
The One Whose mighty hand holds the world sway
Order my life
In ways I’ve been disobedient to You
Father, forgive me, I pray
I’m the river that flows from Your Source; do not let me dry up

Reverence! Reverence!!

The wicked grow, the wicked prosper
The good beg for food
The kind suffer
You do as You please
Your mysterious ways are known only to You; Your glory never tarnishes
The Rock of Ages, I look to You
Man’s wagging tongue is never reliable
Man speaks ill of You; man speaks good of You
The One Who has the days keeps numbering them
Sooner or later, the things of the world will perish with the world

Reverence! Reverence!!

He who gets burnt by a friend’s fire of betrayal keeps what he has in his mind to himself
There is a true friend as such that loves you deeply
There is also such a friend that kills in betrayal
Hope entrusted in man is a blatant lie!
The One Friend I have
God, The Almighty, I reverence You; Father, You’re the Greatest!

Reverence! Reverence!!

*Culled from my song “ÌBÀ”.

Originally posted 2015-10-02 19:50:39. Republished by Blog Post Promoter

Ohun ti mo fẹ́ràn nipa Ìsimi Iparí Ọ̀sẹ̀ – What I love about the Weekend BreakOriginally Posted on July 6, 2018, last updated on July 4, 2018 and reposted on July 23, 2019

Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ karun ti a ti bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé ni ọ̀sẹ̀, inú mi ma ń dùn nitori ilé-iwé ti pari ni agogo kan ọ̀sán, ti ìsimi bẹ̀rẹ̀.

Mo fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma nri àwọn òbí mi.  Lati ọjọ́ Ajé titi dé ọjọ́ Ẹti, mi o ki ri ìyá àti bàbá mi nitori súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ni Èkó, wọn yio ti jade ni ilé ni kùtùkùtù òwúrọ̀ ki n tó ji, wọn yio pẹ́ wọlé lẹhin ti mo bá ti sùn.

Mo tún fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma ńsùn pẹ́, mo tún ma a ńri àyè wo eré lori amóhùn-máwòrán.  Ni àkókò ilé-iwé, mo ni lati ji ni agogo mẹfa òwúrọ̀ lati múra fún ọkọ̀ ilé-iwé ti yio gbé mi ni agogo meje òwúrọ̀.  Ṣùgbọ́n ní igbà ìsimi ipari ọ̀sẹ̀, mo lè sùn di agogo mẹjọ òwúrọ̀.  Ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìyá mi ma nṣe oriṣiriṣi oúnjẹ ti ó dùn, mo tún ma njẹun púpọ̀.  Ni ọjọ́ Àikú (ọjọ́ ìsimi) bàbá mi ma ngbé wa lọ si ilé-ìjọ́sìn, lẹhin isin, a ma nlọ ki bàbá àti ìyá àgbà.  Bàbá àti ìyá àgbà dára púpọ̀.

Ni ọjọ́ Àikú ti ìsimi ti fẹ́ pari, inú mi ki i dùn nigbati òbí mi bá sọ wi pé mo ni lati tètè sùn lati palẹ̀mọ́ fún ilé-iwé ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ajé.

ENGLISH LANGUAGE

On Friday the fifth day of schooling, I am always very happy because school closes at one o’clock in the afternoon when the weekend begins.

I love the weekend break because I get to see my parents.  From Monday to Friday, I do not get to see my mother/mummy and father/daddy because in order to beat the Lagos traffic, they leave home for work before I wake up and return very late when I am asleep.

I also love the weekend break because I get to sleep longer and watch television too.  During the school day, I wake up at six o’clock in the morning to get ready for the school bus that picks me up at seven o’clock in the morning.  But during the weekend, I get to sleep till eight o’clock in the morning.  Mummy cooks different types of meal on Saturday and I get to eat more.  On Sunday, Daddy drives us to Church and after Church, we go to visit my grandparent.  Grandpa and grandma are very nice.

I am not usually happy when I am told by my parent to go to bed early on Sunday in order to get ready for school on Monday.

Originally posted 2018-07-06 01:10:04. Republished by Blog Post Promoter

“Ìwé àti kọ Yorùba lọfẹ lọwọ Àjàyí Crowther Fún Ra Rẹ”: Learn Yoruba for Free From Ajayi CrowtherOriginally Posted on May 23, 2013, last updated on July 2, 2013 and reposted on July 23, 2019

Ise Alagba Yoruba, Ajayi Crowther fun ra re. A Yoruba dictionary to look up basic vocabulary

 

 

Originally posted 2013-05-23 05:38:56. Republished by Blog Post Promoter

Bíbẹ Èkó wo fún Ọ̀sẹ̀ kan – Ọjọ́ kẹta: Visiting Lagos for one week – Day 3 (Yoruba Conversation)Originally Posted on June 4, 2013, last updated on June 7, 2013 and reposted on July 23, 2019

Apá Kinni – Part One

You can also download the conversation by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 3(mp3)

ONÍLÉ – HOST/HOSTESS & ÀLEJÒ (VISITOR)

OHUN ÍṢE

ENGLISH TRANSLATION HOST/HOSTESS AND THE   VISITOR’S ACTIVITIES
ONÍLÉ – HOST Kan ilẹ̀kùn, Ẹkaarọ o, ṣé ẹ ti jí? Knock on the door, Good morning.  Are you awake?
ÀLEJÒ – VISITOR Bẹẹni, mo ti jí, Kaarọ. Yes, I am awake.    Good morning
ONÍLÉ – HOST Ẹjọ̀wọ́ ẹ tètè múra ká lè jáde ni wéré Please dress up quickly to enable us go out on time
 ÀLEJÒ – VISITOR Mo ti ṣe tán, mo mbọ. I have finished dressing, I am coming
ONÍLÉ – HOST Ẹ jẹ́ ká jẹun aarọ kátó jáde lọ si ọjà. Let us eat breakfast before going to the market
ÀLEJÒ – VISITOR Ó da, màá bá ẹ níbi ìjẹun Okay, I will join you at the dining
ONÍLÉ – HOST Ó da, mo nreti.  Iṣu àti ẹyin díndín lafẹ́ jẹ laarọ yi Okay, I am waiting, We are having yam and fried egg   for Breakfast.
ONÍLÉ ATI    – HOST & ÀLEJÒ – VISITOR Ońlé àti Àlejò gba àdúrà, wọ́n sí bẹ̀rẹ̀ sí jẹun The Host/Hostess and the Visitor prayed and they   began to eat
 ÀLEJÒ – VISITOR O ṣé, kú àlejò mi, mo gbádùn oúnjẹ naa Thanks for hosting me, I enjoyed the meal
ONÍLÉ – HOST Ó yá ẹjẹ́ kí á tètè jáde lọ sí ọjà, nítorí ọjà méjì ni á fẹ́ dé. À kọ́kọ́ lọ sí ọjà Tẹ́júoṣó ni Yaba kí a tó padà sí Balógun láti ra àwọn ẹ̀bùn tí ẹ fẹ́ kó padà. Its time, let us go out early to the market   because I want us to get to two markets at Tejuoso in Yaba and Balogun to buy   the gifts you are taking along on your return.
 ÀLEJÒ – VISITOR O ṣé, ó tiyá, jẹ́ ká lọ Thank you.  I   am ready let us go.

 

Originally posted 2013-06-04 17:09:30. Republished by Blog Post Promoter


Orukọ́ Ẹranko àti Àwòrán – Yoruba Names of Animals and picturesOriginally Posted on June 21, 2013, last updated on June 25, 2013 and reposted on July 24, 2019

Bi ọmọ ò jọ ṣòkòtò á jọ kíjìpá: Ibáṣe pọ Idilé Yorùbá – If a child does not take after the father, he/she should take after the mother – Yoruba Family RelationshipOriginally Posted on October 27, 2015 and reposted on July 24, 2019

Bàbá, iyá àti ọmọ ni wọn mọ si Idilé ni Òkè-òkun ṣùgbọ́n ni ilẹ̀ Yorùbá kò ri bẹ́ ẹ̀, nitori ẹbi Eg bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹni, ọmọ, ọkọ àti aya wọn ni a mọ̀ si Idilé.  Yorùbá fẹ́ràn lati má a bọ̀wọ̀ fún àgbà nitori eyi, ẹni ti ó bá ju Bàbá àti Ìyá ẹni lọ Bàbá tàbi Ìyá la n pè é, wọn ki pe àgbà ni orúko nitori eyi, wọn lè fi orúkọ ọmọ pe àgbà tàbi ki wọn lo orúkọ apejuwe (bi Bàbá Èkó, Iyá Ìbàdàn).  Ẹ ṣe à yẹ̀ wò àlàyé àti pi pè ibáṣepọ̀ idilé ni ojú iwé yi.

The Western family is made up of, father, mother and their children but this is not so, as Yoruba family on the other hand is made up of extended family that includes; father, mother, children, half/full brothers/sisters, step children, cousins, aunties, uncles, maternal and paternal grandparents.  Yoruba people love respecting the elders, as a result, uncles and aunties that are older than one’s parents are called ‘Father’ or ‘Mother’ and elders are not called by their names as they are either called by their children’s name or by description (example Lagos Father, Ibadan Mother)  Check the explanation and prononciation below.

Originally posted 2015-10-27 22:57:10. Republished by Blog Post Promoter

BÍBẸ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN: A One Week Visit to a Yoruba Speaking City (Yoruba dialogue inLagos)Originally Posted on March 22, 2013, last updated on March 26, 2013 and reposted on July 25, 2019

These series of posts will center around learning the Yoruba words, phrases and sentences you might come across if you visited a Yoruba speaking city or state (here Lagos). A sample conversation is available for download. We will be posting more conversations. Please leave comments on the blog post, and anything you would like to see or hear covered in this conversation.

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba(mp3)

Use the table below to follow the conversation:

ONÍLÉ – HOST/ HOSTESS ALEJO – VISITOR Ọ̀R SÍS LÃRIN ONÍLÉ ÀTI ÀLEJÒ ENGLISH TRANSLATION: CONVERSATION BETWEEN
THE HOST/HOSTESS AND THE VISITOR
ONÍLÉ Mo fẹ́ lọ pàdé Àlejò ní Ìdíkọ̀-òfúrufú Muritala Mohammed, Èkó I am going to receive a visitor at Muritala Mohammed Airport, Lagos
Àlejò mi tidé My Visitor has arrived
Ẹkáalẹ́ o, ẹkáàbọ̀. Ṣé dãda ni? Good evening, Welcome. Is it well?
ÀLEJÒ Káalẹ́ o. A dúpẹ́ Good evening, Thank you
ONÍLÉ Ṣé ẹ ti rí gbogbo ẹrù yín gbà? Have you collected all your luggage?
ÀLEJÒ Bẹ̃ni. Yes
ONÍLÉ Ó yá, ẹ gbé ẹrù wá, ẹ jẹ́ kí álọ sidi ọkọ̀/mọ́tò Its time, bring your luggage and let us go to the the car
ÀLEJÒ Oṣé, gba ẹrù Thanks, here is my luggage
ONÍLÉ Lọ́nà nínú ọkọ̀. Bawo ni? On the way, in the car. How are you?
ÀLEJÒ Dãda ni, ṣugbọn õru mú. Ó le o, súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ṣi wa lálẹ́ yi? I am fine but there is heat. Its tough, so there is still traffic jam as late?
ONÍLÉ Bẹni, súnkẹrẹ fàkẹrẹ pọ ju bayi lọ lati ãrọ ṣùgbọ́n a o ni pẹ délé mọ.Kílódé Ọlọkada? ṣọ́ra ẹ, ma kọlù ọkọ̀ mí Yes, the traffic was worst in the morning but we will soon get home.What is it motorcylist? Be careful do not hit my car.
ÀLEJÒ Oṣé, kú iṣé o. Thanks, well done.
ONÍLÉ A ti délé. Ẹjẹ́ ká ko ẹrù wọlé. We are home. Lets take the luggage in.
ÀLEJÒ Oṣé gidi gan. Thanks so much.
ONÍLÉ Yàrá tí ẹ ma sùn rẽ, ilé ìwẹ̀ re, bí ẹ bá ẁẹ tán ẹ wá jẹun This is your bedroom, here is the bathroom,when you finish taking your birth, come and eat.
ÀLEJÒ Kíla fẹ́ jẹ? Ebi npa mi What are we eating? I am hungry
ONÍLÉ Iresi ati Dodo ni? Rice and Fried Plantain.
ÀLEJÒ O da bẹ. A dúpẹ́ Its good. Thank you
ONÍLÉ ATI ÀLEJÒ Wọ́n bẹ̀rẹ̀ si jẹun They began to eat
ÀLEJÒ Oṣé o, mo ti yó, ounjẹ nã dùn Thanks, I am full, the food taste good.
ONÍLÉ A dúpẹ́ Thank you
À̀LEJÒ Ó ti rẹ̀ mí, mo fẹ́ lọ sùn I am tired, I want to go and sleep
ONÍLÉ O da bẹ. Ódàárọ̀ o Its fine, goodnight
ÀLEJÒ Ódàárọ̀ Goodnight.

Originally posted 2013-03-22 22:06:42. Republished by Blog Post Promoter

Pi pè àti Orin fún orúkọ ọjọ́ ni èdè Yorùbá – Yoruba Days of the week pronunciation and songOriginally Posted on July 29, 2014, last updated on July 29, 2014 and reposted on July 25, 2019

OrúkỌjọ́ni èdè Yorùbá                 Days of the Week In English

Àìkú/Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀/Ìsimi                            – Sunday

Ajé                                                      – Monday

Ìṣẹ́gun                                                – Tuesday

Ọjọ́rú                                                 – Wednesday

Ọjọ́bọ̀                                                – Thursday

Ẹti                                                      – Friday

Àbámẹ́ta                                            – Saturday

Originally posted 2014-07-29 20:31:30. Republished by Blog Post Promoter

Iwé-àkọ-ránṣẹ́ ni èdè Yorùbá – Letter writing in Yoruba LanguageOriginally Posted on March 11, 2014 and reposted on July 30, 2019

Ni àtijọ́, àwọn ọmọ ilé-iwé ló ńran àgbàlagbà ti kò lọ ilé-iwé lọ́wọ́ lati kọ iwé, pataki ni èdè abínibí.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn iwé-àkọ-ránṣẹ́ wọnyi ni ojú iwé yi:

Ìwé ti Ìyá kọ sí ọmọ

Èsì iwé ti ọmọ kọ si iyá

Iwé ti ọkọ kọ si iyàwó

Èsi iwé ti aya kọ si ọkọ

Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.
Image may be NSFW.
Clik here to view.

ENGLISH TRANSLATION

In the olden days, school children often helped the elderly who were not literate to write letters particularly in the ethnic language.  See samples of letters written in Yoruba below:

Letter from mother to child

20 Afunbiowo Street                                                                                 Akure

20 February, 1969

My dearest child,

Hope you are well as I am here?  Your Father and your younger ones are fine.  Hope your studies are going on fine?

My child “Akanki” do not forget your home.  You will not disappear in your land of sojourn (Amen).  Face your studies.  You will bring in your harvest home.

Extend greetings to your friends.  We shall be expecting your response.

May our meeting be as sweet as honey.

Yours truly,                                                                                                                                         Your mother – Wale’s mother.

Child’s response to mother

Room 24                                                                                                        Fagunwa Hall                                                                                               University of Lagos                                                                                    Akoka, Lagos

March 13, 1969

My Dearest Mother,

How are you and my father?  How is everyone at home?

I am very glad to inform you that I got to my School safely, my studies are going on fine.  School is good, we are fed thrice daily, a big ocean is near our School.  I met one our town’s man whose name is Kayode – from Aro’s family compound.  He has helped me a lot to settle down in School.

I promise you and my father that I will not forget home.

Extend my special greetings to my younger ones ant to my brother Wale too.  Also extend my greetings to my father and everyone at home.

We shall meet joyfully.

Yours truly,                                                                                            Your Son Ibukunolu

Husband’s letter to wife

12 Onabola Street                                                                                       Somolu, Lagos

12 October, 1978

My Dearest wife,

Hope you are well as I am here?  How are my children?  Hope their school is going on well?

I am glad to write you this letter, because I have been allocated an official car and I have secured an accommodation too.  As a result, I will be sending for you all soon.

My love, hope the children are not stressing you?  Tell Aduke that I love her dearly, if I see anyone coming home, I will send her toys.

Take care of the children very well.  Extend my greetings to your mother and my father too.  Greetings to everyone at home.

We shall meet joyfully very soon because I am eager to see my special wife and the children

Goodbye, we meet with happiness.

Your husband truly,                                                                                   Segun’s father

Wife’s response letter to husband in Yoruba

Ajamajebi’s ompound,                                                                              Ilorin

 

16-11-78

My true husband,

I am glad to receive your letter.  We are all fine.  The children are doing well at School.

I am also glad to hear the joyful news that you have been allocated a car in your office and also that you have found an accommodation.  By God’s grace, you will not record an accident with the vehicle.

The children are not giving me too much trouble but Aduke has been asking of her father always.

People at home are all fine.

We shall be getting ready because once the children begins their holiday we would love to join you in Lagos.

My mother sent her greetings.  Father is a bit ill but he getting better little by little.  Greetings from everyone at home.

I am eagerly looking forward to see my husband.

Do take care at work.  We shall with joyfully.

Yours truly,                                                                                                                                         Your wife Ibadi-ileke

Originally posted 2014-03-11 01:14:25. Republished by Blog Post Promoter

Viewing all 1414 articles
Browse latest View live