Quantcast
Channel: Learning Yoruba – The Yoruba Blog
Viewing all 1414 articles
Browse latest View live

“Ẹsẹ̀ yá ju mọ́tọ̀ (ọkọ̀) ara ló nfàbò sí” – ohun ìrìn-àjò ni èdè Yorùbá: “Legs are faster than vehicle wears the body out” – Names of means of travelling in Yoruba LanguageOriginally Posted on August 2, 2013, last updated on August 23, 2013 and reposted on May 22, 2019

$
0
0

Ni ayé àtijọ́ ẹsẹ̀ ni gbogbo èrò ma nlo lati rin lati ìlú kan si keji nigbati ọkọ̀ ìgbà̀lódé kò ti wọpọ.  Ilé Ọba àti Ìjòyè ni a ti le ri ẹṣin nitori ẹṣin kò lè rin ninu igbó kìjikìji ti o yi ilẹ̀ Yorùbá ká. Ọrọ Yorùbá ayé òde òní ni “Ẹsẹ̀ yá ju mọ́tọ̀ (ọkọ̀) ara lo nfàbọ̀ si”.  Ọ̀rọ̀ yi bá àwọn èrò ayé àtijọ́ mu nitori  ìrìn-àjò ti wọn fi ẹsẹ̀ rin fún ọgbọ̀n ọjọ́, ko ju bi wákà̀̀tí mẹ́fà lọ fún ọkọ ilẹ̀ tàbi ogoji ìṣẹ́jú fún ọkọ̀-òfúrufú.

Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ìrìnsẹ̀ ayé àtijọ́ àti ayé òde òní ni èdè Yorùbá, ohun àti àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi.

ENGLISH TRANSLATION

In the olden days, people move about by walking from one place to the other, this was before the advent of the modern means of transportation.  Horses were only found in the Kings and Chief’s house due to the ecology of the Yoruba region which is surrounded by thick forest.  According to the modern Yoruba adage “Legs are faster than vehicle wears the body out”.  This can be applied to the ancient people because the journey that they had to walk for thirty (30) days is not more than six (6) hours journey in a car or forty (40) minutes by air.

View the slide below on this page for the Yoruba names of means of travelling in the olden and modern times:

OHUN ÌRÌNÀJO – Means of Transport Slides

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2013-08-02 17:36:34. Republished by Blog Post Promoter


ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in YorubaOriginally Posted on March 22, 2018, last updated on March 22, 2018 and reposted on May 28, 2019

Kòkòrò – Names of Insects & Bugs in YorubaOriginally Posted on January 29, 2014, last updated on January 29, 2014 and reposted on May 29, 2019

$
0
0

Kòkòrò jẹ́ ohun ẹ̀dá kékeré tó ni ìyẹ́, ti ó lè fò, òmíràn kò ni iyẹ́, ṣugbọn wọn ni ẹsẹ̀ mẹfa.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ, àwòrán àti pi pè ni ojú ewé wọnyi.

ENGLISH TRANSLATION

Insects & Bugs are small creatures, many of them have feathers, some have no feathers, but they have six legs.  Check out the examples in the pictures and the pronunciation on the slides below:

Originally posted 2014-01-29 01:18:16. Republished by Blog Post Promoter

Orukọ́ Ẹranko àti Àwòrán – Yoruba Names of Animals and picturesOriginally Posted on June 21, 2013, last updated on June 25, 2013 and reposted on May 30, 2019

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in YourubaOriginally Posted on October 17, 2014, last updated on October 16, 2014 and reposted on June 2, 2019

Orúkọ Gbogbo Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá – Names of part of Human Body in YorubaOriginally Posted on August 1, 2016, last updated on August 1, 2016 and reposted on June 3, 2019

$
0
0

Nitotọ àti ṣe ẹ̀yà orí tẹlẹ ṣugbọn a lérò wípé orúkọ gbogbo ẹ̀yà ara lati orí dé ẹsẹ á wúlò fún kíkà.

Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá and the English Translation of names of part of the body

Though the names of parts of the head had earlier been published but we think the readers will find the names of the whole body from head to toe will be useful for reading

 

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2016-08-01 12:05:50. Republished by Blog Post Promoter

BÍBẸ̀ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN (ỌJỌ́ KEJÌ) – Visiting Lagos for a Week (Day 2)Originally Posted on April 5, 2013, last updated on April 11, 2013 and reposted on June 3, 2019

$
0
0

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 2(mp3)

JỌ́ KEJÌ – DAY TWO
ONÍLÉ (HOST OR HOSTESS) ÀLEJÒ (VISITOR) Ọ̀RỌ̀ SÍS LÃRIN ONÍLÉ ÀTI ÀLEJÒ ENGLISH TRANSLATION: CONVERSATION   BETWEEN THE HOST/HOSTESS AND THE VISITOR
ONÍLÉ – HOST Kan ilẹ̀kùn Knock on the door
ÀLEJÒ (VISITOR) Tani? Who is it?
ONÍLÉ – HOST Èmi ni o.    Ẹkãrọ, ṣé ẹ sùn dãda? It is me.    Goodmorning.  Hope you slept   well?
ÀLEJÒ (VISITOR) Bẹ̃ni, mo sùn dãda, a dúpẹ́ Yes, I slept well, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ãgo meje ti lù, mo fẹ́ má lọ si ibi iṣẹ́. It is seven o’clock, I want to go to work
ÀLEJÒ (VISITOR) Ah, ãgo meje ti sáré lù, mo mbọ mo ti múra tán Ah! Its already 7 a.m?  I am coming, I have finished dressing
ONÍLÉ – HOST Ó da, mò ndúró.    Oúnje ãrọ ti ṣetán Okay, I am waiting, breakfast is ready.
ÀLEJÒ (VISITOR) Kíla fẹ́ jẹ lãrọ yi? What are we eating this morning?
ONILE – HOST Ògì àti àkàrà ni.    Ó yá, ẹ jẹ́ká jẹun It is Indian Corn Starch and Fried Bean Cake
Onílé àti Àlejò gba àdúrà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹun The Host/Hostess and Visitor prayed and they began to eat
ÀLEJÒ (VISITOR) O se, ku alejo mi, mo gbadun ounje na. Fi abọ́ sílẹ̃, ma palẹ̀mọ́. Thanks for hosting me, I enjoyed the meal.  Leave the plates, I will clear up.
ONÍLÉ – HOST Mo ti fẹ́ mã lọ si ibi iṣẹ́.    Mo ti gbé ẹ̀wà rírò àti gãri si ibi ìdáná fún oúnjẹ ọ̀sán.    Tí ẹ bá́́ simi tán ti ẹ fẹ́ najú ladugbo, ẹ pe Folúṣọ́ ní ilé keji kó sì yín jáde. I am about going to work, I have kept stewed beans   and gari (coarsed casava flour) in the kitchen for lunch.  If you want to take a stroll around the   neigbhourhood, call Foluso from the next house to accompany you.
ÀLEJÒ (VISITOR) O ṣé, ódàbọ̀. Ó rẹ̀ mí, mã sùn díẹ̀ si ṣùgbọ́n ma pe Folúṣọ́ tí mo bájí Thank you.    Goodbye.  I am tired, I will   sleep a little later and call Foluso when I wake.
ONÍLÉ – HOST Ódàbọ̀.    Mà ṣetán níbi iṣẹ ni ãgo marun àbọ̀. Ó yẹ ki ndélé títí ãgo meje tíkò bá sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ Goodbye.  I   will close from work at 5.30pm.  I hope   to get home at about 7.00pm if there is no traffic jam.
ÀLEJÒ (VISITOR) O da bẹ. A dú́pẹ́ Its fine, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ẹkúilé o.  Ṣé ẹ simi dãda? Greetings.    Hope you had a good rest?
ÀLEJÒ (VISITOR) Kãbọ, ó mà yá, o ti dé lãgo mẹ́fà àbọ̀.    Mo simi dãda, Folúṣọ́ mú mi jáde sí Àdúgbò. Welcome, your return at 6.30pm was quick.  I went around the neighbourhood with   Foluso.
ONÍLÉ – HOST Bẹ̃ni, kò sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ rárá. Ṣé ebi ti npa yín? Yes, there was no traffic jam at all.  Are you hungry?
ÀLEJÒ (VISITOR) Rárá, mo ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ ọ̀sán tí ó gbé sílẹ̀ ni bi ãgo mẹ́fà ni. No, I have just eaten the lunch you left for me at about 6.00pm.
ONÍLÉ – HOST O dã bẹ.    Èmi nã ti jẹun níbiṣẹ́.  Mo ma lọ palẹ̀mọ́ lati sùn ṣùgbọ́n mi o lọ síbi iṣẹ́ lọla  a ṣeré jáde. Ódàárọ̀. That is good. I have also eaten at work.  I am going    to get ready to sleep but I am not going to work tomorrow, we will go   for outing. Goodnight.
ÀLEJÒ (VISITOR) Ódàárọ̀ Goodnight.

Originally posted 2013-04-05 20:52:07. Republished by Blog Post Promoter

KÍKÀ NÍ YORÙBÁ: COUNTING IN YORUBA – NUMBERS 1 TO 20Originally Posted on March 12, 2013, last updated on March 18, 2013 and reposted on June 4, 2019

$
0
0

KÍKÀ ỌJÀ NIPARI Ọ̀SẸ̀ – END OF WEEK STOCK TAKING: LEARNING NUMBERS 1 TO 20

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: counting 1 -20 in Yoruba recited

0 Òdo Àlùbọ́sà titán Zero onions (Out of Stock)
1 Õkan Àpò Iyọ̀ kan One bag of salt
2 Ẽji Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ méjì Two bunches of bananas
3 Ẹ̃ta Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀  àgbagbà mẹ́ta Three bunches of Plantains
4 Ẹ̃rin Garawa Epo Òyìnbó mẹ́rin Four tins of kerosene
5 Ãrun Garawa Òróró marun Five tins of vegetable oil
6 Ẹ̀fà Garawa Epo pupa mẹ́fà Six tins of palm oil
7 Ẽje Igo Epo Òyìnbó meje Seven bottles of kerosene
8 Ẹ̀jo Igo Òróró mj Eight bottles of vegetable oil
9 Ẹ̀sán Igo Epo pupa msan Nine bottles of palm Oil
10 Ẹ̀wá Ẹja gbígbẹ mwa Ten pieces of dry fish
11 Ọ̀kànlá Àpò Ẹ̀wà mọ́kànlá Eleven bags of beans
12 Èjìlá Àpò Èlùbọ́ méjìlá Twelve bags of dry yam flour
13 Ẹ̀tàlá Àpò Ìrẹsì mẹ́tàlá Thirteen bags of rice
14 Ẹ̀rìnlá Àpò Gãri mẹ́rìnlá Fourteen bags of coarse cassava flour
15 Mẹ̃dogun Àpò Àgbàdo mẹ̃dogun Fifteen bags of maize
16 Ẹ̀rìndínlógún Iṣu mẹ́rìndínlógún Sixteen yams
17 Ẹ̀tàdínlógún Àgbọn mẹ́tàdínlógún Seventeen coconuts
18 Èjìdínlógún Orógbó méjìdínlógún Eighteen pods of bitter kola
19 Ọ̀kàndínlógún Atare mọ́kàndínlógún Nineteen alligator peppers
20 Ogún Obì Ogún Twenty kola nuts

Originally posted 2013-03-12 22:25:14. Republished by Blog Post Promoter


“ABD” ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè Yorùbá́ – Alphabets is the beginning of words in Yoruba LanguageOriginally Posted on February 4, 2014, last updated on February 4, 2014 and reposted on June 5, 2019

$
0
0

Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa “abd” ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kikọ ni èdè Yorùbá sẹhin, a tu kọ fún iranti rẹ ni pi pè, kikọ àti lati tọka si ìyàtọ̀ larin ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́si.

Fún àpẹrẹ, èdè Gẹ̀ẹ́si ni ibere oro mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nigbati èdè Yorùbá ni marun-din-lọgbọn.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn àwòrán ti o wa ni oju ewe wonyi:

ENGLISH TRANSLATION

Even though we have written about Yoruba Alphabets in the past, it is being re-written to remind  readers on how it is pronounced, written and to point out the difference between the Yoruba and English Alphabets.

For example, English Alphabets are made up of twenty-six letter while Yoruba Alphabets are twenty-five.  Check out the slides on this page.

Diference between Yoruba & English Alphabets

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2014-02-04 19:04:40. Republished by Blog Post Promoter

“Ògòngò lọba ẹiyẹ” – “Ostrich is the King of Birds”Originally Posted on October 17, 2014, last updated on October 16, 2014 and reposted on June 10, 2019

$
0
0
Ògòngò - Ostrich.  Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò – Ostrich. Courtesy: @theyorubablog

Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù.  Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku.  Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀.  Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ.  Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nitori bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn.

Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé (ẹiyẹ ọsin)ni, Adiẹ (Àkùkọ àti Àgbébọ̀ adiẹ), Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó/Odidẹrẹ́ àti Ọ̀kín.  Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni: Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Igún/Àkàlàmàgbò àti Lekeleke.  Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn.  Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi.

Agbe ló laró ————— ki rá ùn aró
Àlùkò ló losùn ———— ki rá ùn osùn
Lekeleke ló lẹfun ——– ki rá ùn ẹfun
Ka má rá ùn owó, ka má rá ùn ọmọ
Ohun tá ó jẹ, tá ó mu, kò mà ni wọn wa ò.

ENGLISH TRANSLATION

Ostrich is the biggest and has the largest eggs among the birds.  The long neck and legs made it taller than all the other birds.  Ostrich is also the fastest runner on land more than all the birds.  This is why Yoruba crowned Ostrich as the King of Birds.  Many wild birds such as Ostrich are almost extinct as a result of the expansion of towns and cities displacing the wild birds which can now be seen at the Zoo.

There are various types of birds in Yoruba land, the most common at home or in town (domestic birds) are: Chicken (Cock and Hen), Duck, Pigeon, Guinea Fowl, Parrot, and Peacock.  The common wild birds that are known in the town or communities are: Falcon/Kite, Eagle, Owl, Vulture and Cattle-egret.  Birds are of various colours, one species of bird can come in various colours, while some are black like the dye, some are red like the camwood, and some are white, but the Yoruba song on this page depicted the common colours that are peculiar with some species of birds.  For example, Cattle-Egret are white like chalk, Blue Turaco are coloured like the dye and Red Turaco are reddish like the camwood.   Check out the pictures and prononciation of some of the birds that are common in Yoruba land on this page.

Originally posted 2014-10-17 12:27:16. Republished by Blog Post Promoter

Bíbẹ Èkó wo fún Ọ̀sẹ̀ kan – Ọjọ́ kẹta: Visiting Lagos for one week – Day 3 (Yoruba Conversation)Originally Posted on June 4, 2013, last updated on June 7, 2013 and reposted on June 10, 2019

$
0
0

Apá Kinni – Part One

You can also download the conversation by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 3(mp3)

ONÍLÉ – HOST/HOSTESS & ÀLEJÒ (VISITOR)

OHUN ÍṢE

ENGLISH TRANSLATION HOST/HOSTESS AND THE   VISITOR’S ACTIVITIES
ONÍLÉ – HOST Kan ilẹ̀kùn, Ẹkaarọ o, ṣé ẹ ti jí? Knock on the door, Good morning.  Are you awake?
ÀLEJÒ – VISITOR Bẹẹni, mo ti jí, Kaarọ. Yes, I am awake.    Good morning
ONÍLÉ – HOST Ẹjọ̀wọ́ ẹ tètè múra ká lè jáde ni wéré Please dress up quickly to enable us go out on time
 ÀLEJÒ – VISITOR Mo ti ṣe tán, mo mbọ. I have finished dressing, I am coming
ONÍLÉ – HOST Ẹ jẹ́ ká jẹun aarọ kátó jáde lọ si ọjà. Let us eat breakfast before going to the market
ÀLEJÒ – VISITOR Ó da, màá bá ẹ níbi ìjẹun Okay, I will join you at the dining
ONÍLÉ – HOST Ó da, mo nreti.  Iṣu àti ẹyin díndín lafẹ́ jẹ laarọ yi Okay, I am waiting, We are having yam and fried egg   for Breakfast.
ONÍLÉ ATI    – HOST & ÀLEJÒ – VISITOR Ońlé àti Àlejò gba àdúrà, wọ́n sí bẹ̀rẹ̀ sí jẹun The Host/Hostess and the Visitor prayed and they   began to eat
 ÀLEJÒ – VISITOR O ṣé, kú àlejò mi, mo gbádùn oúnjẹ naa Thanks for hosting me, I enjoyed the meal
ONÍLÉ – HOST Ó yá ẹjẹ́ kí á tètè jáde lọ sí ọjà, nítorí ọjà méjì ni á fẹ́ dé. À kọ́kọ́ lọ sí ọjà Tẹ́júoṣó ni Yaba kí a tó padà sí Balógun láti ra àwọn ẹ̀bùn tí ẹ fẹ́ kó padà. Its time, let us go out early to the market   because I want us to get to two markets at Tejuoso in Yaba and Balogun to buy   the gifts you are taking along on your return.
 ÀLEJÒ – VISITOR O ṣé, ó tiyá, jẹ́ ká lọ Thank you.  I   am ready let us go.

 

Originally posted 2013-06-04 17:09:30. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀YÀ ARA – ÈJÌKÁ DÉ ẸSẸ̀: PARTS OF THE BODY – SHOULDERS TO TOESOriginally Posted on April 23, 2013, last updated on May 4, 2013 and reposted on June 11, 2019

$
0
0

You can also download the mp3 by right clicking here: Parts of the body in Yoruba – shoulders to toes (mp3)

Ẹ̀YÀ ARA PARTS   OF THE BODY
Èjìká Shoulder
Abíyá Armpit
Apá Arms
Ìgunpá Elbow
Ọrùnọwọ́ Wrist
Ọwọ́ Hand
Ìkaọwọ́ Fingers
Ẽkanna Nails
Àtẹlẹwọ Palm of the hand
Atampako Thumb
Àyà Chest
Ọyàn Breast/Bust
Ẹ̀gbẹ́ Side
Ẹ̀hìn Back
Ikùn Stomach
Ìdodo Navel   or Belly button
Ìbàdí Lower   back
Ìdí Butttocks
Ẹsẹ̀ Legs
Ẽkún Knee
Ọrùnẹsẹ̀ Ankle
Ẹsẹ̀ Legs
Àtẹ́lẹsẹ̀ Sole   of the foot
Ìkaẹsẹ̀ Toes

Originally posted 2013-04-23 21:34:14. Republished by Blog Post Promoter

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter HolidayOriginally Posted on June 15, 2018, last updated on June 15, 2018 and reposted on June 12, 2019

$
0
0

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos.

Lagos is a very big city, with many tall buildings, so much various vehicles than in my home town.  My uncle’s house is very big.  I was given a room to myself.  My room had a bathroom and toilet of its own.

My father and mother took me to Ikare-Akoko garage in Ondo State where I boarded public transport to Lagos and from that experience, I discovered that Lagos is so far from my home town.  Among the towns I saw on the way were, Owo, Akure, Ile-Ife and Ibadan.  We stopped over at Ilesa junction to buy bean fritters. My uncle and his wife were at hand at Ojota motor-park in Lagos to drive me to their home.

Every day, my uncle and his wife took me on a visit to various places in Lagos.  On Good Friday, I was taken to church, the service was a sober one as a play on the crucifixion of Jesus was acted, but on Easter Sunday, the service was beautiful as there were many gaily dressed people in the church. I wore one of the newly clothes my uncle’s wife bought for me for Easter celebration.  From the Sunday school, we as children joined the main church with dancing.  At the end of the church service we were all served food (containing rice and big chicken lap).  On Easter Monday (known as Galilee), we went for picnic at the beach.  At first I was afraid of seeing such a large expanse of body of water, but later as I noticed that there were many people including children at the beach, my fear was gone.  We ate different types of food, we danced and I rode a horse at the beach.

The school holiday was almost over, after two weeks, my uncle and his wife took me back to the bus terminal with various gifts for people at my home town.  I was sad, I did not want to go back to my home town because I had so much fun in Lagos.

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter

“Ti ibi, ti ire la wá ilé ayé” –Ọ̀rọ̀ àti Ìṣe Ìgboro ni Èkó: “We came into the world with good and bad” – Street Talk and Activities in LagosOriginally Posted on September 24, 2013, last updated on September 24, 2013 and reposted on June 12, 2019

$
0
0

Èkó jẹ́ olú ìlú Nigeria fún ọpọlọpọ ọdún, ki wọn tó sọ Abuja di olú ìlú Nigeria, ṣùgbọ́n Èkó ṣi jẹ́ olú ìlú fún iṣẹ ọrọ̀ gbogbo Nigeria.  Nitori eyi, gbogbo ẹ̀yà Nigeria àti àwọn ará ìlú miran titi dé òkè-òkun/ìlú-òyinbó ló wà ni Èkó.

Yorùbá ni èdè ti wọn nsọ ni ìgboro Èkó, ṣùgbọ́n ọpọlọpọ gbọ èdè Gẹẹsi, pataki àwọn ti ki ṣé ọmọ Yorùbá.  Ẹ wo díẹ̀ ni àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ ni ìgboro Èkó:

ENGLISH TRANSLATION

Lagos was the capital of Nigeria for many years before the capital was moved to Abuja, but Lagos remains the commercial capital of Nigeria.  As a result, every ethnic group in Nigeria and people from abroad/Europe are present in Lagos.

Originally posted 2013-09-24 19:43:17. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé làbọ̀sinmi oko” – “Home is for rest after the farm or hard day’s work”.Originally Posted on August 13, 2013, last updated on December 11, 2014 and reposted on June 12, 2019

$
0
0

Bi ènìà lówó tàbi bi kò ni, àwọn ohun kan ṣe pàtàki lati wà ni ílé ki a tó lè pẽ ibẹ̀ ni ilé.  Fún àpẹrẹ: ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé; àdìrò àti àdògán; omi: Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ.

Yorùbá ni “ilé làbọ̀sinmi oko”, lẹhin iṣẹ́ õjọ, ó ṣe pàtàkì lati ni ilé ti ènìà yio darí si.  Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi.

ENGLISH LANGUAGE

Whether a person is rich or poor, there are some basic things that are important in a house before it can be called a home.  For example: A house with a roof, door and windows; kitchen and cooking utensils; water: either pipe borne water, rain water or a well and food are all very important in a home.

Yoruba adage said “Home is for rest after the farm or a hard day’s work, hence it is important to have a house for a person to return to.  Check out the names and pictures of many household items on this page.

 

 

Originally posted 2013-08-13 11:20:51. Republished by Blog Post Promoter


Ìkíni ni Èdè Yorùbá – Greetings in Yoruba LanguageOriginally Posted on July 4, 2013, last updated on September 27, 2014 and reposted on June 16, 2019

$
0
0

Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀  Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si abala ojú     ìwé yi,  àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò  fún yin.

ENGLISH TRANSLATION

As a sign of respect, the Yoruba have greetings for any time of the day, special events and ceremonies. We hope you will enjoy some of the greetings below in the slides and voice recordings.

Originally posted 2013-07-04 23:41:35. Republished by Blog Post Promoter

ATỌ́NÀ LÉDÈ YORÙBÁ – Cardinal Directions in YorubaOriginally Posted on April 16, 2013, last updated on August 18, 2015 and reposted on June 16, 2019

$
0
0
Compass with Yoruba labels

A compass showing the poles in Yoruba language. The image is courtesy of @theyorubablog

 

Originally posted 2013-04-16 19:01:07. Republished by Blog Post Promoter

“Ìwé àti kọ Yorùba lọfẹ lọwọ Àjàyí Crowther Fún Ra Rẹ”: Learn Yoruba for Free From Ajayi CrowtherOriginally Posted on May 23, 2013, last updated on July 2, 2013 and reposted on June 17, 2019

$
0
0

Ise Alagba Yoruba, Ajayi Crowther fun ra re. A Yoruba dictionary to look up basic vocabulary

 

 

Originally posted 2013-05-23 05:38:56. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀kọ́-ìṣirò ni èdè Yorùbá – Simple Arithmetic in Yoruba LanguageOriginally Posted on March 22, 2016, last updated on April 8, 2016 and reposted on June 17, 2019

$
0
0

Yorùbá ni bi wọn ti ma nṣe ìṣirò ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ka ni èdè Gẹ̀ẹ́sì.  Akọ̀wé yi kọ ìṣirò ki ó tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé lọdọ ìyá rẹ̀ àgbà.  Nígbàtí ìyá-àgbà bá nṣe iṣẹ́ òwú “Sányán” lọ́wọ́, a ṣa òkúta wẹ́wẹ́ fún ọmọ-ọmọ rẹ̀ lati ṣe ìṣirò ni èdè Yorùbá.  Is̀irò ni èdè Yorùbá ti fẹ́ di ohun ìgbàgbé, nitori àwọn ọmọ ayé òde òní kò rí ẹni kọ́ wọn ni ilé tàbi ilé-ìwé, nitorina ni a ṣe ṣe àkọọ́lẹ̀ ìṣirò yi si ojú ewé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba were doing Arithmetic before learning it in English.  This Publisher learnt simple Arithmetic from her grandmother before enrolling in primary school.  As the Grandmother was processing “raw silk”, she would gather pebbles for her granddaughter for the purpose of teaching simple Arithmetic in Yoruba Language.  Arithmetic in Yoruba Language is almost extinct, because children nowadays, have no one to teach them at home or at school, hence the documentation of these simple Arithmetic in Yoruba Language as can be viewed on this page.

Originally posted 2016-03-22 07:10:47. Republished by Blog Post Promoter

Bi ọmọ ò jọ ṣòkòtò á jọ kíjìpá: Ibáṣe pọ Idilé Yorùbá – If a child does not take after the father, he/she should take after the mother – Yoruba Family RelationshipOriginally Posted on October 27, 2015 and reposted on June 17, 2019

$
0
0

Bàbá, iyá àti ọmọ ni wọn mọ si Idilé ni Òkè-òkun ṣùgbọ́n ni ilẹ̀ Yorùbá kò ri bẹ́ ẹ̀, nitori ẹbi Eg bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹni, ọmọ, ọkọ àti aya wọn ni a mọ̀ si Idilé.  Yorùbá fẹ́ràn lati má a bọ̀wọ̀ fún àgbà nitori eyi, ẹni ti ó bá ju Bàbá àti Ìyá ẹni lọ Bàbá tàbi Ìyá la n pè é, wọn ki pe àgbà ni orúko nitori eyi, wọn lè fi orúkọ ọmọ pe àgbà tàbi ki wọn lo orúkọ apejuwe (bi Bàbá Èkó, Iyá Ìbàdàn).  Ẹ ṣe à yẹ̀ wò àlàyé àti pi pè ibáṣepọ̀ idilé ni ojú iwé yi.

The Western family is made up of, father, mother and their children but this is not so, as Yoruba family on the other hand is made up of extended family that includes; father, mother, children, half/full brothers/sisters, step children, cousins, aunties, uncles, maternal and paternal grandparents.  Yoruba people love respecting the elders, as a result, uncles and aunties that are older than one’s parents are called ‘Father’ or ‘Mother’ and elders are not called by their names as they are either called by their children’s name or by description (example Lagos Father, Ibadan Mother)  Check the explanation and prononciation below.

Originally posted 2015-10-27 22:57:10. Republished by Blog Post Promoter

Viewing all 1414 articles
Browse latest View live