Quantcast
Channel: Learning Yoruba – The Yoruba Blog
Viewing all 1414 articles
Browse latest View live

Ohun ti mo fẹ́ràn nipa Ìsimi Iparí Ọ̀sẹ̀ – What I love about the Weekend BreakOriginally Posted on July 6, 2018, last updated on July 4, 2018 and reposted on April 12, 2019

$
0
0

Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ karun ti a ti bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé ni ọ̀sẹ̀, inú mi ma ń dùn nitori ilé-iwé ti pari ni agogo kan ọ̀sán, ti ìsimi bẹ̀rẹ̀.

Mo fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma nri àwọn òbí mi.  Lati ọjọ́ Ajé titi dé ọjọ́ Ẹti, mi o ki ri ìyá àti bàbá mi nitori súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ni Èkó, wọn yio ti jade ni ilé ni kùtùkùtù òwúrọ̀ ki n tó ji, wọn yio pẹ́ wọlé lẹhin ti mo bá ti sùn.

Mo tún fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma ńsùn pẹ́, mo tún ma a ńri àyè wo eré lori amóhùn-máwòrán.  Ni àkókò ilé-iwé, mo ni lati ji ni agogo mẹfa òwúrọ̀ lati múra fún ọkọ̀ ilé-iwé ti yio gbé mi ni agogo meje òwúrọ̀.  Ṣùgbọ́n ní igbà ìsimi ipari ọ̀sẹ̀, mo lè sùn di agogo mẹjọ òwúrọ̀.  Ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìyá mi ma nṣe oriṣiriṣi oúnjẹ ti ó dùn, mo tún ma njẹun púpọ̀.  Ni ọjọ́ Àikú (ọjọ́ ìsimi) bàbá mi ma ngbé wa lọ si ilé-ìjọ́sìn, lẹhin isin, a ma nlọ ki bàbá àti ìyá àgbà.  Bàbá àti ìyá àgbà dára púpọ̀.

Ni ọjọ́ Àikú ti ìsimi ti fẹ́ pari, inú mi ki i dùn nigbati òbí mi bá sọ wi pé mo ni lati tètè sùn lati palẹ̀mọ́ fún ilé-iwé ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ajé.

ENGLISH LANGUAGE

On Friday the fifth day of schooling, I am always very happy because school closes at one o’clock in the afternoon when the weekend begins.

I love the weekend break because I get to see my parents.  From Monday to Friday, I do not get to see my mother/mummy and father/daddy because in order to beat the Lagos traffic, they leave home for work before I wake up and return very late when I am asleep.

I also love the weekend break because I get to sleep longer and watch television too.  During the school day, I wake up at six o’clock in the morning to get ready for the school bus that picks me up at seven o’clock in the morning.  But during the weekend, I get to sleep till eight o’clock in the morning.  Mummy cooks different types of meal on Saturday and I get to eat more.  On Sunday, Daddy drives us to Church and after Church, we go to visit my grandparent.  Grandpa and grandma are very nice.

I am not usually happy when I am told by my parent to go to bed early on Sunday in order to get ready for school on Monday.

Originally posted 2018-07-06 01:10:04. Republished by Blog Post Promoter


Ẹ̀̀ya orí ni èdè Yorùbá – Parts of Head in Yoruba LanguageOriginally Posted on July 16, 2013, last updated on July 16, 2013 and reposted on April 12, 2019

$
0
0

Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀.  Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè.  A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò.

ENGLISH TRANSLATION

It is important to be familiar with the names of parts of the body in learning a language because it is often embedded in conversation.  Understanding these names would enhance the knowledge of Yoruba by those who love to learn the language.  We hope that the pictures and the Yoruba pronunciation on these slides would be useful.

Originally posted 2013-07-16 01:52:39. Republished by Blog Post Promoter

“Ìwé àti kọ Yorùba lọfẹ lọwọ Àjàyí Crowther Fún Ra Rẹ”: Learn Yoruba for Free From Ajayi CrowtherOriginally Posted on May 23, 2013, last updated on July 2, 2013 and reposted on April 13, 2019

$
0
0

Ise Alagba Yoruba, Ajayi Crowther fun ra re. A Yoruba dictionary to look up basic vocabulary

 

 

Originally posted 2013-05-23 05:38:56. Republished by Blog Post Promoter

Tọ́jú Ìwà Rẹ Ọ̀rẹ́ Mi – Ọ̀rọ̀-orin lati Ìwé Olóògbé Olóyè J.F. Ọdúnjọ – My friend, care about your character – a poem by late Chief J.F. OdunjoOriginally Posted on August 10, 2018, last updated on August 10, 2018 and reposted on April 15, 2019

$
0
0

Ọ̀rọ̀-orin yi jẹ ikan ninú àwọn àkọ́-sórí ni ilé-ìwé alakọbẹrẹ ni ilẹ̀ Yorùbá ni igbà ti ile-iwe àpapọ̀ yè koro.  Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ti gbogbo ilé-ìwé ti kọ èdè abínibí silẹ̀, ọ̀rọ̀-orin ti kò ni ìtumọ̀ ni àṣà àti èdè Yorùbá ni àwọn ọmọ ilé-ìwé ńkà.  Tàbi bawo ni “afárá tó wó lulẹ̀ ni ìlú-ọba” ṣe kan ọmọ ti kò ri iná, omi mímọ́ mu, ọ̀nà gidi, ilé-ìwé ti idaji rẹ ti wó, tàbi ti kò ri afárá ri ni abúlé rẹ̀, ti jẹ́?  A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ti ó ṣe òfin ki wọn bẹ̀rẹ̀ si kọ́ èdè àti àṣà Yorùbá ni gbogbo ilé-ìwé pátápátá.  A lérò wi pé eleyi yi o jẹ́ ki àwọn olùkọ́ àti ọmọ ilé-ìwé bẹ̀rẹ̀ si kọ́ ọ̀rọ̀-orin tàbi àkọ́-sórí ti ó mú ọgbọ́n dáni.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò ki kọ àti ki kà  ọ̀rọ̀-orin yi.

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi;
Ọlá a má ṣi lọ n’ilé ẹni’
Ẹwà a si ma ṣi l’ára ènìà

Olówó òní ńd’olòṣì b’ó d’ọ̀la
Òkun l’ọlá; òkun n’igbi ọrọ̀
Gbogbo wọn ló ńṣí lọ n’ilé ẹni;
Ṣùgbọ́n ìwà̀ ni mbá ni dé sare’e
Owó kò jẹ́ nkan fún ni,
Ìwà l’ẹwà ọmọ ènìà.

Bi o lówó bi o kò n’íwà ńkọ́?
Tani jẹ f’inú tán ẹ bá ṣ’ohun rere?
Tàbi ki o jẹ́ obìnrin rọ̀gbọ̀dọ́;
Ti o bá jìnà s’ìwà ti ẹ̀dá ńfẹ́,
Tani jẹ́ fẹ́ ọ s’ílé bi aya?
Tàbi ki o jẹ oníjìbìtì ènìà;
Bi o tilẹ̀ mọ ìwé àmọ̀dájú,
Tani jẹ́ gbé’ṣé ajé fún ọ ṣe?

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi,
Ìwà kò sí, ẹ̀kọ́ dègbé;
Gbogbo ayé ni ‘nfẹ́ ‘ni t’ó jẹ́ rere.

ENGLISH TRANSLATION

This is one of the poems memorised by primary school pupils when there was quality public education.  But nowadays, when schools have abandoned mother tongue, children are now taught meaningless foreign poems.  Or how relevant is the poem about “London Bridge falling down” to a child who has no access to electricity/power, clean potable water, good road, dilapidated classrooms, or has never seen a bridge in her little village?  Kudos to the Lagos House of Assembly and the Governor for legislating a law making the teaching and learning of Yoruba language and culture compulsory in all Lagos schools.  It is hoped that this effort by Lagos State will encourage both the teachers and pupils to return to learning poems that are relevant and sensible poems.  See below the words and recital of the poem.

Care about your character, my friend;
Wealth do depart from one’s lineage
Beauty do fade from people

A rich man today could end up in poverty tomorrow,
Riches is like ocean, ocean is like the depth of wealth
All do depart from lineage
But only character follows one to the grave
Money is nothing
Character is the beauty of a person

What if you are rich without any moral principle?
Who will confide in you for a worthy cause?
Or if you are a woman of paragon beauty;
Yet far away from people’s expected moral standard,
Who will marry such as a wife?
Or if you are a con-artist;
Even when you are highly educated,
Who will entrust you with business?

Care about your character, my friend,
In the absence of character, education is futile,
Everyone loves a person with good character.

Originally posted 2018-08-10 02:12:55. Republished by Blog Post Promoter

“ABD” ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ni èdè Yorùbá́ – Alphabets is the beginning of words in Yoruba LanguageOriginally Posted on February 4, 2014, last updated on February 4, 2014 and reposted on April 15, 2019

$
0
0

Bi ó ti ẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ nipa “abd” ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kikọ ni èdè Yorùbá sẹhin, a tu kọ fún iranti rẹ ni pi pè, kikọ àti lati tọka si ìyàtọ̀ larin ọ̀rọ̀ Yorùbá àti ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́si.

Fún àpẹrẹ, èdè Gẹ̀ẹ́si ni ibere oro mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nigbati èdè Yorùbá ni marun-din-lọgbọn.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn àwòrán ti o wa ni oju ewe wonyi:

ENGLISH TRANSLATION

Even though we have written about Yoruba Alphabets in the past, it is being re-written to remind  readers on how it is pronounced, written and to point out the difference between the Yoruba and English Alphabets.

For example, English Alphabets are made up of twenty-six letter while Yoruba Alphabets are twenty-five.  Check out the slides on this page.

Diference between Yoruba & English Alphabets

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2014-02-04 19:04:40. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀YÀ ARA – ÈJÌKÁ DÉ ẸSẸ̀: PARTS OF THE BODY – SHOULDERS TO TOESOriginally Posted on April 23, 2013, last updated on May 4, 2013 and reposted on April 15, 2019

$
0
0

You can also download the mp3 by right clicking here: Parts of the body in Yoruba – shoulders to toes (mp3)

Ẹ̀YÀ ARA PARTS   OF THE BODY
Èjìká Shoulder
Abíyá Armpit
Apá Arms
Ìgunpá Elbow
Ọrùnọwọ́ Wrist
Ọwọ́ Hand
Ìkaọwọ́ Fingers
Ẽkanna Nails
Àtẹlẹwọ Palm of the hand
Atampako Thumb
Àyà Chest
Ọyàn Breast/Bust
Ẹ̀gbẹ́ Side
Ẹ̀hìn Back
Ikùn Stomach
Ìdodo Navel   or Belly button
Ìbàdí Lower   back
Ìdí Butttocks
Ẹsẹ̀ Legs
Ẽkún Knee
Ọrùnẹsẹ̀ Ankle
Ẹsẹ̀ Legs
Àtẹ́lẹsẹ̀ Sole   of the foot
Ìkaẹsẹ̀ Toes

Originally posted 2013-04-23 21:34:14. Republished by Blog Post Promoter

Ìbà Àkọ́dá – Reverence to the First BeingOriginally Posted on October 2, 2015, last updated on October 2, 2015 and reposted on April 18, 2019

$
0
0
Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá - A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá – A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá
Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ
Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ
Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ
Alápáńlá tó so’lé ayé ró
Ṣe àtúntò ayé mi
Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ
Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀
Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ

Ìbà! ìbà!!

Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú
Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ
Ọmọ onínúure a má a pọ́njú
Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ
Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́
Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o
Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé
Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere
Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́
Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ

Ìbà! ìbà!!

Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò
ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú
ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu
Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú!
ọ̀rẹ́ kan tí mo ní
Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù!

Ìbà! ìbà!!

ENGLISH TRANSLATION

Reverence to the First Being, reverence to the Creator
I will revere Him today; let my reverence be
In times of plenty, in times of scarcity
I come with a heart of thanksgiving; let my reverence be
The One Whose mighty hand holds the world sway
Order my life
In ways I’ve been disobedient to You
Father, forgive me, I pray
I’m the river that flows from Your Source; do not let me dry up

Reverence! Reverence!!

The wicked grow, the wicked prosper
The good beg for food
The kind suffer
You do as You please
Your mysterious ways are known only to You; Your glory never tarnishes
The Rock of Ages, I look to You
Man’s wagging tongue is never reliable
Man speaks ill of You; man speaks good of You
The One Who has the days keeps numbering them
Sooner or later, the things of the world will perish with the world

Reverence! Reverence!!

He who gets burnt by a friend’s fire of betrayal keeps what he has in his mind to himself
There is a true friend as such that loves you deeply
There is also such a friend that kills in betrayal
Hope entrusted in man is a blatant lie!
The One Friend I have
God, The Almighty, I reverence You; Father, You’re the Greatest!

Reverence! Reverence!!

*Culled from my song “ÌBÀ”.

Originally posted 2015-10-02 19:50:39. Republished by Blog Post Promoter

ORÚKỌ ỌJỌ́: Days of the Week in YorubaOriginally Posted on March 19, 2013, last updated on March 26, 2013 and reposted on April 18, 2019

$
0
0

Below are the Yoruba days of the week. Of course it is worth noting that very few native Yoruba speakers use these words in conversation.

 

SUNDAY                               ÀÌKÚ

MONDAY                             AJÉ

TUESDAY                             ÌṢẸ́GUN

WEDNESDAY                      ỌJỌ́RÚ

THURSDAY                          ỌJỌ́BỌ̀

FRIDAY                                 ẸTÌ

SATURDAY                          ÀBÁMẸ́TA

Originally posted 2013-03-19 22:33:05. Republished by Blog Post Promoter


Orukọ́ Ẹranko àti Àwòrán – Yoruba Names of Animals and picturesOriginally Posted on June 21, 2013, last updated on June 25, 2013 and reposted on April 19, 2019

“Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi: Ibere ti ó wọ́pọ́ ni èdè Yorùba” – “Questions calls for answer: Common questions in Yoruba language”Originally Posted on January 13, 2015, last updated on January 12, 2015 and reposted on April 20, 2019

$
0
0

Ọpọlọpọ ibere ni èdè Yorùbá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu “ọfọ̀ – K”.  Yàtọ̀ fún li lò ọfọ̀ yi ninú ọ̀rọ̀, orúkọ enia tàbi ẹranko, ọfọ̀ yi wọ́pọ̀ fún li lò fún ibere.  Fún àpẹrẹ, orúkọ enia ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọfọ̀ – K ni: Kíkẹ́lọmọ, Kilanko, Kẹlẹkọ, Kẹ́mi, Kòsọ́kọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ; orúkọ ẹranko – Kiniun, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Kòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn irú ibere àti èsì wọnyi ni ojú ewé yi.

Ìsọ̀rọ̀ ni igbèsi – Slides

View more presentations or Upload your own.

[slideboom id=1069722&w=425&h=370]

Originally posted 2015-01-13 09:00:46. Republished by Blog Post Promoter

BÍBẸ̀ ÈKÓ WÒ FÚN Ọ̀SẸ̀ KAN (ỌJỌ́ KEJÌ) – Visiting Lagos for a Week (Day 2)Originally Posted on April 5, 2013, last updated on April 11, 2013 and reposted on April 22, 2019

$
0
0

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A conversation in Yoruba – Day 2(mp3)

JỌ́ KEJÌ – DAY TWO
ONÍLÉ (HOST OR HOSTESS) ÀLEJÒ (VISITOR) Ọ̀RỌ̀ SÍS LÃRIN ONÍLÉ ÀTI ÀLEJÒ ENGLISH TRANSLATION: CONVERSATION   BETWEEN THE HOST/HOSTESS AND THE VISITOR
ONÍLÉ – HOST Kan ilẹ̀kùn Knock on the door
ÀLEJÒ (VISITOR) Tani? Who is it?
ONÍLÉ – HOST Èmi ni o.    Ẹkãrọ, ṣé ẹ sùn dãda? It is me.    Goodmorning.  Hope you slept   well?
ÀLEJÒ (VISITOR) Bẹ̃ni, mo sùn dãda, a dúpẹ́ Yes, I slept well, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ãgo meje ti lù, mo fẹ́ má lọ si ibi iṣẹ́. It is seven o’clock, I want to go to work
ÀLEJÒ (VISITOR) Ah, ãgo meje ti sáré lù, mo mbọ mo ti múra tán Ah! Its already 7 a.m?  I am coming, I have finished dressing
ONÍLÉ – HOST Ó da, mò ndúró.    Oúnje ãrọ ti ṣetán Okay, I am waiting, breakfast is ready.
ÀLEJÒ (VISITOR) Kíla fẹ́ jẹ lãrọ yi? What are we eating this morning?
ONILE – HOST Ògì àti àkàrà ni.    Ó yá, ẹ jẹ́ká jẹun It is Indian Corn Starch and Fried Bean Cake
Onílé àti Àlejò gba àdúrà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jẹun The Host/Hostess and Visitor prayed and they began to eat
ÀLEJÒ (VISITOR) O se, ku alejo mi, mo gbadun ounje na. Fi abọ́ sílẹ̃, ma palẹ̀mọ́. Thanks for hosting me, I enjoyed the meal.  Leave the plates, I will clear up.
ONÍLÉ – HOST Mo ti fẹ́ mã lọ si ibi iṣẹ́.    Mo ti gbé ẹ̀wà rírò àti gãri si ibi ìdáná fún oúnjẹ ọ̀sán.    Tí ẹ bá́́ simi tán ti ẹ fẹ́ najú ladugbo, ẹ pe Folúṣọ́ ní ilé keji kó sì yín jáde. I am about going to work, I have kept stewed beans   and gari (coarsed casava flour) in the kitchen for lunch.  If you want to take a stroll around the   neigbhourhood, call Foluso from the next house to accompany you.
ÀLEJÒ (VISITOR) O ṣé, ódàbọ̀. Ó rẹ̀ mí, mã sùn díẹ̀ si ṣùgbọ́n ma pe Folúṣọ́ tí mo bájí Thank you.    Goodbye.  I am tired, I will   sleep a little later and call Foluso when I wake.
ONÍLÉ – HOST Ódàbọ̀.    Mà ṣetán níbi iṣẹ ni ãgo marun àbọ̀. Ó yẹ ki ndélé títí ãgo meje tíkò bá sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ Goodbye.  I   will close from work at 5.30pm.  I hope   to get home at about 7.00pm if there is no traffic jam.
ÀLEJÒ (VISITOR) O da bẹ. A dú́pẹ́ Its fine, thank you.
ONÍLÉ – HOST Ẹkúilé o.  Ṣé ẹ simi dãda? Greetings.    Hope you had a good rest?
ÀLEJÒ (VISITOR) Kãbọ, ó mà yá, o ti dé lãgo mẹ́fà àbọ̀.    Mo simi dãda, Folúṣọ́ mú mi jáde sí Àdúgbò. Welcome, your return at 6.30pm was quick.  I went around the neighbourhood with   Foluso.
ONÍLÉ – HOST Bẹ̃ni, kò sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ rárá. Ṣé ebi ti npa yín? Yes, there was no traffic jam at all.  Are you hungry?
ÀLEJÒ (VISITOR) Rárá, mo ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ ọ̀sán tí ó gbé sílẹ̀ ni bi ãgo mẹ́fà ni. No, I have just eaten the lunch you left for me at about 6.00pm.
ONÍLÉ – HOST O dã bẹ.    Èmi nã ti jẹun níbiṣẹ́.  Mo ma lọ palẹ̀mọ́ lati sùn ṣùgbọ́n mi o lọ síbi iṣẹ́ lọla  a ṣeré jáde. Ódàárọ̀. That is good. I have also eaten at work.  I am going    to get ready to sleep but I am not going to work tomorrow, we will go   for outing. Goodnight.
ÀLEJÒ (VISITOR) Ódàárọ̀ Goodnight.

Originally posted 2013-04-05 20:52:07. Republished by Blog Post Promoter

Orúkọ Ẹranko a fàyà fà tabi jomijòkè ni èdè Yorùbá: Names of Reptiles and Amphibious Animals in Yoruba LanguageOriginally Posted on December 27, 2013 and reposted on April 23, 2019

$
0
0

Gẹgẹbi àpè júwe, ẹranko a fàyà fà jẹ ẹranko ti ó ni àwọ̀, omiran ni oro, omiran ni ikarawun, wọn si ńyé ẹyin.  Bi Ejò, àti Ákẽke ti ni oró bẹ̃ ni Àjàpá  àti Ìgbín ni ikarawun. Fún àpẹrẹ irú àwọn ẹran wọnyi ni: Ejò, Àjàpá, Alangba àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Ẹ wo àwòrán àti pipe irú àwọn ẹranko wọnyi ni ojú ewé yi.

ENGLISH TRANSLATION

According to the description, reptiles are animals with skin, some are poisonous, while some have shell and lay eggs.  As snake and scorpion are poisonous so also are the tortoise and snail have shell.  For example: Snakes, Tortoise, lizard etc.  Check out the pictures and pronunciation of these reptiles in the slides below.

Ẹranko a fàyà fà tabi jomijòkè – Reptiles

View more presentations or Upload your own.

Originally posted 2013-12-27 00:26:23. Republished by Blog Post Promoter

ATỌ́NÀ LÉDÈ YORÙBÁ – Cardinal Directions in YorubaOriginally Posted on April 16, 2013, last updated on August 18, 2015 and reposted on April 23, 2019

$
0
0
Compass with Yoruba labels

A compass showing the poles in Yoruba language. The image is courtesy of @theyorubablog

 

Originally posted 2013-04-16 19:01:07. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in YorubaOriginally Posted on March 22, 2018, last updated on March 22, 2018 and reposted on April 24, 2019

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in YourubaOriginally Posted on October 17, 2014, last updated on October 16, 2014 and reposted on April 25, 2019


“Ilé làbọ̀sinmi oko” – “Home is for rest after the farm or hard day’s work”.Originally Posted on August 13, 2013, last updated on December 11, 2014 and reposted on May 2, 2019

$
0
0

Bi ènìà lówó tàbi bi kò ni, àwọn ohun kan ṣe pàtàki lati wà ni ílé ki a tó lè pẽ ibẹ̀ ni ilé.  Fún àpẹrẹ: ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé; àdìrò àti àdògán; omi: Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ.

Yorùbá ni “ilé làbọ̀sinmi oko”, lẹhin iṣẹ́ õjọ, ó ṣe pàtàkì lati ni ilé ti ènìà yio darí si.  Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi.

ENGLISH LANGUAGE

Whether a person is rich or poor, there are some basic things that are important in a house before it can be called a home.  For example: A house with a roof, door and windows; kitchen and cooking utensils; water: either pipe borne water, rain water or a well and food are all very important in a home.

Yoruba adage said “Home is for rest after the farm or a hard day’s work, hence it is important to have a house for a person to return to.  Check out the names and pictures of many household items on this page.

 

 

Originally posted 2013-08-13 11:20:51. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán àti pi pè orúkọ ẹ̀yà ara lati ori dé ọrùn – Pictures and pronunciation of parts of the body from head to neckOriginally Posted on November 13, 2015, last updated on November 10, 2015 and reposted on May 3, 2019

KÍKÀ NÍ YORÙBÁ: COUNTING IN YORUBA – NUMBERS 1 TO 20Originally Posted on March 12, 2013, last updated on March 18, 2013 and reposted on May 4, 2019

$
0
0

KÍKÀ ỌJÀ NIPARI Ọ̀SẸ̀ – END OF WEEK STOCK TAKING: LEARNING NUMBERS 1 TO 20

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: counting 1 -20 in Yoruba recited

0 Òdo Àlùbọ́sà titán Zero onions (Out of Stock)
1 Õkan Àpò Iyọ̀ kan One bag of salt
2 Ẽji Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ méjì Two bunches of bananas
3 Ẹ̃ta Pádi Ọ̀gẹ̀dẹ̀  àgbagbà mẹ́ta Three bunches of Plantains
4 Ẹ̃rin Garawa Epo Òyìnbó mẹ́rin Four tins of kerosene
5 Ãrun Garawa Òróró marun Five tins of vegetable oil
6 Ẹ̀fà Garawa Epo pupa mẹ́fà Six tins of palm oil
7 Ẽje Igo Epo Òyìnbó meje Seven bottles of kerosene
8 Ẹ̀jo Igo Òróró mj Eight bottles of vegetable oil
9 Ẹ̀sán Igo Epo pupa msan Nine bottles of palm Oil
10 Ẹ̀wá Ẹja gbígbẹ mwa Ten pieces of dry fish
11 Ọ̀kànlá Àpò Ẹ̀wà mọ́kànlá Eleven bags of beans
12 Èjìlá Àpò Èlùbọ́ méjìlá Twelve bags of dry yam flour
13 Ẹ̀tàlá Àpò Ìrẹsì mẹ́tàlá Thirteen bags of rice
14 Ẹ̀rìnlá Àpò Gãri mẹ́rìnlá Fourteen bags of coarse cassava flour
15 Mẹ̃dogun Àpò Àgbàdo mẹ̃dogun Fifteen bags of maize
16 Ẹ̀rìndínlógún Iṣu mẹ́rìndínlógún Sixteen yams
17 Ẹ̀tàdínlógún Àgbọn mẹ́tàdínlógún Seventeen coconuts
18 Èjìdínlógún Orógbó méjìdínlógún Eighteen pods of bitter kola
19 Ọ̀kàndínlógún Atare mọ́kàndínlógún Nineteen alligator peppers
20 Ogún Obì Ogún Twenty kola nuts

Originally posted 2013-03-12 22:25:14. Republished by Blog Post Promoter

Àròkọ ni Èdè Yorùbá – Essay in Yoruba LanguageOriginally Posted on June 15, 2018, last updated on June 15, 2018 and reposted on May 6, 2019

$
0
0

Idi ti a fi bẹ̀rẹ̀ si kọ iwé ni èdè Yorùbá lóri ayélujára ni lati jẹ́ ki ẹnikẹ́ni ti ó fẹ́ mọ̀ nipa èdè àti àṣà Yorùbá ri ìrànlọ́wọ́ lóri ayélujára.

A ò bẹ̀rẹ̀ si kọ àwọn àròkọ ni èdè Yorùbá lati ran àwọn ọmọ ilé-iwé lọ́wọ́ nipa ki kọ àpẹrẹ oriṣiriṣi àròkọ ni èdè Yorùbá àti itumọ̀ rẹ ni èdè Gẹ̀ẹ́si.  A o si tún ka a ni èdè Yorùbá fún ìrànlọ́wọ́ ẹni ti ó fẹ mọ bi ohun ti lè ka a, ṣùgbọ́n kò wà fún àdàkọ.

ENGLISH TRANSLATION

Why The Yoruba Blog is creating a category for Essay in Yoruba language on the internet is to make available on line such resources for those who may be interested.

We shall begin to publish various samples of essay in Yoruba language in order to assist students, interpreted the essay as well as an audio recording of the essay in Yoruba, however, it is not to be copied.

Originally posted 2018-06-15 19:19:46. Republished by Blog Post Promoter

Ìkíni ni Èdè Yorùbá – Greetings in Yoruba LanguageOriginally Posted on July 4, 2013, last updated on September 27, 2014 and reposted on May 6, 2019

$
0
0

Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀  Fún àpẹrẹ: a lérò wípé àwọn ti a kọ si abala ojú     ìwé yi,  àti bi a ti le pe ìkíni kankan a wúlò  fún yin.

ENGLISH TRANSLATION

As a sign of respect, the Yoruba have greetings for any time of the day, special events and ceremonies. We hope you will enjoy some of the greetings below in the slides and voice recordings.

Originally posted 2013-07-04 23:41:35. Republished by Blog Post Promoter

Viewing all 1414 articles
Browse latest View live